1 Mo sì yípadà, mo sì gbé ojú mi sòkè, mo sì wò, sì kíyèsi i, kẹ̀kẹ́ mẹ́rin jáde wá láti àárin òkè-ńlá méjì, àwọn òkè-ńlà náà sì jẹ́ òkè-ńlà idẹ.
2 Àwọn ẹṣin pupa wà ní kẹ̀kẹ́ èkínní; àti àwọn ẹṣin dúdú ní kẹ̀kẹ́ èkejì.
3 Àti àwọn ẹṣin funfun ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹta; àti àwọn adíkálà àti alágbára ẹṣin ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹrin.
4 Mo sì dáhùn, mo sì béèrè lọ́wọ́ ańgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni ìwọ̀nyí, Olúwa mi.”
5 Ańgẹ́lì náà si dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀mí mẹ́rin ti ọ̀run, tí wọn ń lọ kúrò lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn hàn níwájú Olúwa gbogbo ayé.
6 Àwọn ẹṣin dúdú tí ó wà nínú rẹ̀ jáde lọ sí ilẹ̀ àríwá; àwọn funfun sì jáde tẹ̀lé wọn; àwọn adíkálà sì jáde lọ sí ìhà ilẹ̀ gúsù.”
7 Àwọn alágbára ẹṣin sì jáde lọ, wọ́n sì ń wá ọ̀nà àti lọ kí wọn báa lè rìn síhín-sọ́hùnún ni ayé; ó sì wí pé, “Ẹ lọ, ẹ lọ rìn síhìn-sọ́hùn ní ayé!” Wọ́n sì rín síhìnín-sọ́hùnún ní ayé.
8 Nígbà náà ni ohùn kan sì ké sí mi, ó sì bá mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wò ó, àwọn wọ̀nyí tí ó lọ síhà ilẹ̀ àríwá ti mú ẹ̀mí mi parọ́rọ́ ni ilẹ̀ àríwá.”
9 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé:
10 “Mú nínú ìgbèkùn, nínú àwọn Hélídáì, tí Tóbíyà, àti ti Jédáyà, tí ó ti Bábílónì dé, kí ìwọ sì wá ní ọjọ́ kan náà, kí o sì wọ ilé Jósáyà ọmọ Séfánáyà lọ.
11 Kí o sì mú sílifà àti wúrà, kí o sì fi ṣe adé púpọ̀, sì gbé wọn ka orí Jóṣúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà.
12 Sì sọ fún un pé: ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogún sọ wí pé, wo ọkùnrin náà ti orukọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀ka; yóò sì yọ ẹ̀ka láti abẹ́ rẹ̀ wá, yóò si kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa wa.
13 Òun ni yóò sì kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa òun ni yóò sì wọ̀ ní ògo, yóò sì jókòó, yóò sì jọba lorí ìtẹ́ rẹ̀; òun ó sì jẹ́ àlùfáà lorí ìtẹ́ rẹ̀; ìmọ̀ àlàáfíà yóò sì wá láàrin àwọn méjèèje.’
14 Adé wọ̀nyí yóò sì wà fún Hélémù àti fún Tóbíyà, àti fún Jédíà, àti fún Hénì ọmọ Sefanáyà fún irántí ni tẹ́ḿpìlì Olúwa.
15 Àwọn tí ó jìnnà réré yóò wá láti kọ́ tẹ́ḿpìlì Olúwa, ẹ̀yiń o sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti rán mi sí yín. Yóò sì rí bẹ́ẹ̀ bí ẹ̀yín o bá gbà ohùn Olúwa, Ọlọ́run yín gbọ́ nítootọ́.”