Sekaráyà 4 BMY

Ọ̀pá Fìtílà Wúrà Àti Àwọn Igi Ólífì Méjì

1 Ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ sì tún dé, ó sì jí mi, bí ọkùnrin tí a jí lójú oorun rẹ̀,

2 Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?”Mo sì wí pé, “Mo wò, sì kíyèsí i, ọ̀pá fìtílà tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ wúrà, pẹ̀lú àwokòtò rẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú fìtílà méje rẹ̀ lórí rẹ̀, àti ẹnu méje fún fìtílà méjèèje, tí ó wà lórí rẹ̀:

3 Igi ólífì méjì sì wà létí rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwokòtò náà, àti èkejì ní apá òsì rẹ̀.”

4 Mo sì dáhùn mo sì wí fún ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀, pé, “Kín ni wọ̀nyí, Olúwa mi?”

5 Ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?”Mo sì wí pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n, Olúwa mi.”

6 Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Serubábélì tó wí pé: ‘Kìí ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò se nípa Ẹ̀mí mi,’ ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí

7 “Ta ni ìwọ, ìwọ òkè ńlá? Ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú Serubábélì: òun yóò sì fi ariwo mú òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yóò máa kígbe wí pé, ‘Ọlọ́run bùkún-un Ọlọ́run bùkún-un!’ ”

8 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé:

9 “Ọwọ́ Serubábélì ni a ti ṣe ipilẹ̀ ilé yìí, ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì parí rẹ̀; ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí i yín.

10 “Ṣùgbọ́n ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré? Nítorí wọn ó yọ̀ ní, ìwọ̀n lọ́wọ́ Serubábélì.“(Àwọn méje wọ̀nyí ni àwọn ojú Olúwa, tí ó ń sáré síhìn ín sọ́hùn ún ní gbogbo ayé.)”

11 Mo sì béèrè, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn igi ólífì méjì wọ̀nyí jásí, tí ó wà ní apá ọ̀tún fìtílà àti ní apá òsì rẹ̀?”

12 Mo sì tún dáhùn, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn ẹ̀ka méjì igi wọ̀nyí jásí, tí ń tú òróró wúrà jáde nínú ara wọn láti ẹnu ọ̀pá oníhò wúrà méjì.”

13 Ó sì dáhùn, ó wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?”Mo sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, Olúwa à mi.”

14 Ó sì wí pé, “Àwọn méjì wọ̀nyí ni àwọn tí a fi òróró yàn, tí ó dúró ti Olúwa gbogbo ayé.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14