Sekaráyà 10:1-7 BMY

1 Ẹ bèèrè òjò nígbà àrọ̀kúrò ni ọwọ́ Olúwa; Olúwa tí o dá mọ̀nàmọ́ná,tí ó sì fi ọ̀pọ̀ òjò fún ènìyàn,fún olúkúlúkù koríko ní pápá.

2 Nítorí àwọn òrìṣà tí sọ̀rọ̀ asán,àwọn aláfọ̀ṣẹ sì tí rí èké,wọn sì tí rọ àlá èké;wọ́n ń tu ni nínú láṣán,nítorí náà àwọn ènìyàn náà ṣáko lọ bí àgùntàn,a ṣẹ wọn níṣẹ̀ẹ́, nítorí Olùṣọ́àgùntàn kò sí.

3 “Ìbínú mi ru sí àwọn darandaran,èmi o sì jẹ àwọn olórí níyànítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti bẹ agbo rẹ̀,ilé Júdà wò,yóò ṣi fi wọn ṣe ẹṣin rẹ̀ dáradára ní ogun.

4 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni òkúta igun ilé ti jáde wá,láti ọ̀dọ̀ rẹ ni igi-èèkàn àgọ́ tí wá,láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrún ogun tí wá,láti ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn akóniṣiṣẹ́ gbogbo tí wá.

5 Gbogbo wọn yóò sì dàbí ọkùnrinalágbára ni ogun tí ń tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro, wọn ó sì jagun,nítorí Olúwa wà pẹ̀lú wọn,wọn ó sì dààmú àwọn tí ń gun ẹṣin.”

6 “Èmi o sì mú ilé Júdà ní agbára,èmi o sì gba ilé Jósẹ́fù là,èmi ó sì tún mú wọn padànítorí mo tí ṣàánú fún wọn,ó sì dàbí ẹni pé èmi kò ì tìí ta wọ́n nù;nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn,èmi o sì gbọ́ ti wọn

7 Éfúráímù yóò sì ṣe bí alágbára,ọkàn wọn yóò sì yọ̀ bi ẹni pé nípa ọtí-wáìnì:àní àwọn ọmọ wọn yóò rí í,wọn o sì yọ̀, inú wọn ó sì dùn nínú Olúwa.