8 Èmi ó kọ sí wọn, èmi ó sì ṣà wọ́n jọ;nítorí èmi tí rà wọ́n padà;wọn ó sì pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bíwọ́n tí ń pọ̀ sí í rí.
9 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo tú wọn kákiri orílẹ̀-èdè:ṣíbẹ̀ wọn ó sì rántí mi ni ilẹ̀ jínjìn;wọn ó sì gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn,wọn ó sì tún padà.
10 Èmi ó sì tún mú wọn padà kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítìpẹ̀lú, èmi ó sì ṣà wọn jọ kúrò ni ilẹ̀ Áṣíríà:èmi ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ Gílíádì àti Lébánónì; aa kì yóò sì rí àyè fún wọn bí ó ti yẹ.
11 Wọn yóò sì la òkun wàhálà já,yóò sì lu rírú omi nínú òkun,gbogbo ibú odò ni yóò sì gbẹ,a ó sì rẹ ìgbéraga Áṣíríà ṣílẹ̀,ọ̀pá aládé Éjíbítì yóò sí lọ kúrò.
12 Èmi ó sì mú wọn ní agbára nínú Olúwa;wọn ó sì rìn sókè rìn sódò ni orúkọ rẹ̀,”ni Olúwa wí.