1 Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ sílẹ̀, ìwọ Lébánónì,kí iná bá lè jẹ igi Kédárì rẹ run,
2 Pohùnréré-ẹkún, igi fírì;nítorí igi Kédárì ṣubú,nítorí tí a ba àwọn igi tí o lógo jẹ́:ṣunkún kíkorò ẹ̀yin igi óákù tí Básánì,nítorí gé igbó àjàrà lulẹ̀.
3 Gbọ́ ohun igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn;ògo wọn bàjẹ́;gbọ́ ohùn bíbú àwọn ọmọ kìnnìúnnítorí ògo Jódánì bàjẹ́.
4 Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run mi wí: “Bọ́ ọ̀wọ́-ẹran àbọ́pa.