13 Olúwa sì wí fún mi pé, “Ṣọ ọ sí àpótí ìsúra!” Iye dáradára náà, tí wọn yọ owó mi sí. Mo sì mu ọgbọ̀n owo fàdákà náà, mo sì sọ wọ́n sí àpótí ìsúra ní ilé Olúwa.
14 Mo sì ṣẹ́ ọ̀pá mi kejì, àní Àmùrè, sí méjì, kí èmi lè ya ìbátan tí ó wà láàrin Júdà àti láàrin Íṣírẹ́lì.
15 Olúwa sì wí fún mi pé, “Tún mú ohun-èlò Olùṣọ́-àgùntàn búburú kan ṣọ́dọ̀ rẹ̀.
16 Nítorí Èmi o gbé olùṣọ́-àgùntàn kan dídé ni ilẹ̀ náà, tí kí yóò bẹ àwọn tí ó ṣègbé wò, ti kì yóò sì wá èyí tí ó yapa; tí kì yóò ṣe ìtọ́jú èyí tí a pa lára tàbí kí ó bọ́ àwọn tí ara wọn dá pépé: Ṣùgbọ́n òun yóò jẹ ẹran èyi tí ó ni ọ̀rá, yóò sì fa èékánna wọn ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
17 “Ègbé ni fún olùṣọ́-àgùntàn aṣán náà,tí ó fi ọ̀wọ́-ẹran sílẹ́!Idà yóò ge apá rẹ̀ àti ojú ọ̀tún rẹ̀:apá rẹ̀ yóò gbẹ pátapáta,ojú ọ̀tún rẹ̀ yóò sì fọ́ pátapáta!”