1 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa fún Íṣírẹ́lì, ni Olúwa wí, ẹni tí ó na àwọn ọ̀run, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé ṣọlẹ̀, tí ó sì da ẹ̀mi ènìyàn tí ń bẹ ni inú rẹ̀:
2 “Kíyèsí í, èmi yóò ṣọ Jérúsálẹ́mù dí àgọ́ ìwárìrì sí gbogbo ènìyàn yíká, nígbà tí wọn yóò dó ti Júdà àti Jérúsálẹ́mù.
3 Ní ọjọ́ náà, nígbà tí gbogbo orilẹ̀-èdè ayé bá parapọ̀ sí i, ni èmi yóò sọ Jérúsálẹ́mù di ẹrù òkúta fún gbogbo ènìyàn: gbogbo àwọn tí ó bá sì fi dẹ́rù pa ara wọn ni a ó ge sí wẹ́wẹ́,
4 ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí, “Ni èmi yóò fí ìdágìrì lu gbogbo ẹṣin, àti fi òmùgọ̀ kọlu ẹni tí ń gun un; èmi yóò sì sí ojú mi sí ilé Júdà, èmi yóò sì bu ìfọ́jú lu gbogbo ẹṣin tí orílẹ̀-èdè.
5 Àti àwọn baálẹ̀ Júdà yóò sì wí ni ọkàn wọn pé, ‘Àwọn ara Jérúsálẹ́mù ni agbára mi nípa Olúwa Ọlọ́run wọn.’