11 Ní ọjọ́ náà ni ẹkún, ńláńlá yóò wà ni Jérúsálẹ́mù, gẹ́gẹ́ bí ọ̀fọ̀ Hádádì Rímónì ni àfonífojì Mégídónì.
12 Ilẹ̀ náà yóò ṣọ̀fọ̀, ìdílé, ìdílé, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; ìdílé Dáfídì lọ́tọ̀; àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀; ìdílé Nátanì lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ́.
13 Ìdílé Léfì lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀; ìdílé Ṣimei lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀.
14 Gbogbo àwọn ìdílé tí o kù, ìdílé, ìdílé, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀.