Sekaráyà 12:4-10 BMY

4 ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí, “Ni èmi yóò fí ìdágìrì lu gbogbo ẹṣin, àti fi òmùgọ̀ kọlu ẹni tí ń gun un; èmi yóò sì sí ojú mi sí ilé Júdà, èmi yóò sì bu ìfọ́jú lu gbogbo ẹṣin tí orílẹ̀-èdè.

5 Àti àwọn baálẹ̀ Júdà yóò sì wí ni ọkàn wọn pé, ‘Àwọn ara Jérúsálẹ́mù ni agbára mi nípa Olúwa Ọlọ́run wọn.’

6 “Ní ọjọ́ náà, ni èmi yóò se àwọn baálẹ̀ Júdà bí ààrò iná kan láàrin igi, àti bi ẹfúùfù iná láàrin ìtí; wọn yóò sì jẹ gbogbo àwọn ènìyàn run yíká lápá ọ̀tún àti lápá òsì: a ó sì tún máa gbé inú Jérúsálẹ́mù ní ipò rẹ̀.

7 “Olúwa pẹ̀lú yóò kọ́ tètè gba àgọ́ Júdà là ná, kí ògo ilé Dáfídì àti ògo àwọn ara Jérúsálẹ́mù má ba gbé ara wọn ga sí Júdà.

8 Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò dáàbò bò àwọn tí ń gbé Jérúsálẹ́mù; ẹni tí ó bá sì ṣe àìlera nínú wọn ní ọjọ́ náà, yóò dàbí Dáfídì; ilé Dáfídì yóò sì dàbí Ọlọ́run, bí ańgẹ́lì Olúwa níwájú wọn.

9 Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, èmi yóò wá láti pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè run tí ó wá kọjú ìjà sí Jérúsálẹ́mù.”

10 “Èmi ó sì tu ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bẹ̀ ṣórí ilé Dáfídì àti sórí Jérúsálẹ́mù: wọn ó sì máa wo ẹni tí wọn tí gún ni ọ̀kọ̀, wọn ó sì máa sọ̀fọ̀ rẹ̀, bí ẹnìkan ti ń sọ̀fọ̀ fún ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo àti gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí wọn yóò sì wà ni ìbànújẹ́, bí ẹni tí ń banújẹ́ fún àkọ́bí rẹ̀.