13 Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò wà láàrin wọn; wọn ó sì di ọwọ́ ara wọn mú, ọwọ́ ìkínní yóò sì dìde sì ọwọ́ ìkejì rẹ̀.
14 Júdà pẹ̀lú yóò sì jà ni Jérúsálẹ́mù: ọrọ̀ gbogbo awọn aláìkọlà tí ó wà káàkiri ni a ó sì kójọ, góòlu, àti fàdákà, àti aṣọ, ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.
15 Bẹ́ẹ̀ ni àrùn ẹṣin, ìbáákà, ràkúnmí, àti tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, yóò sì wà, àti gbogbo ẹranko tí ń bẹ nínú àgọ́ wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí àrùn yìí.
16 Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ẹni tí o kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó dìde sí Jérúsálẹ́mù yóò máa gòkè lọ lọ́dọọdún láti sìn Ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti láti ṣe àjọyọ̀ àṣè àgọ́ náà.
17 Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí kì yóò gòkè wá nínú gbogbo ìdílé ayé sí Jérúsálẹ́mù láti sín Ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, òjò kì yóò rọ̀ fún wọn.
18 Bí ìdílé Éjíbítì kò bá sì gòkè lọ, tí wọn kò sì wá, fi ara wọn hàn tí wọn kò ní òjò; àrùn náà yóò wà, tí Olúwa yóò fi kọlù àwọn aláìkọlà tí kò gòkè wá láti se àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà
19 Èyí ni yóò sì jẹ́ ìyà Éjíbítì, àti ìyà gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò gòkè wá láti pa àsè àgọ́ mọ́.