17 Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí kì yóò gòkè wá nínú gbogbo ìdílé ayé sí Jérúsálẹ́mù láti sín Ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, òjò kì yóò rọ̀ fún wọn.
18 Bí ìdílé Éjíbítì kò bá sì gòkè lọ, tí wọn kò sì wá, fi ara wọn hàn tí wọn kò ní òjò; àrùn náà yóò wà, tí Olúwa yóò fi kọlù àwọn aláìkọlà tí kò gòkè wá láti se àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà
19 Èyí ni yóò sì jẹ́ ìyà Éjíbítì, àti ìyà gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò gòkè wá láti pa àsè àgọ́ mọ́.
20 Ní ọjọ́ náà ni “MÍMỌ́ SÍ Olúwa” yóò wà lára ṣaworo ẹṣin: àti àwọn ìkòkò ni ilé Olúwa yóò sì dàbí àwọn ọpọ́n tí ń bẹ níwájú pẹpẹ.
21 Nítòótọ́, gbogbo ìkòkò ni Jérúsálẹ́mù àti ni Júdà yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun: àti gbogbo àwọn tí ń rubọ yóò wá, wọn ó sì mú ìkòkò díẹ̀, wọn ó sì bọ ẹran wọn nínú rẹ̀, ni ọjọ́ náà ni àwọn Kénánì kò ní sí mọ́ ni ile Olúwa àwọn ọmọ-ogun.