Sekaráyà 14:4-10 BMY

4 Ẹṣẹ̀ rẹ̀ yóò sì dúró ni ọjọ́ náà lórí òkè Ólífì, tí ó wà níwájú Jérúsálẹ́mù ni ila-oòrùn, òkè Ólífì yóò sì làá sí méjì, sí ìhà ilà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrun, àfonífojì ńláńlá yóò wà: ìdajì òké náà yóò sì sí síhà àríwá, àti ìdajì rẹ̀ síhà gúṣù.

5 Ẹ̀yin ó sì ṣá sí àfonífojì àwọn òkè mi: nítorí pé àfonífojì òkè náà yóò dé Àṣàlì: nítòòtọ́, ẹ̀yin ó ṣá bí ẹ tí ṣá fún ìmímì-ilẹ̀ ni ọjọ́ Úṣáyà ọba Júdà: Olúwa Ọlọ́run mi yóò sì wá, àti gbogbo àwọn Ẹni-mímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.

6 Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìmọ́lẹ̀ kì yóò mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ṣókùnkùn.

7 Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ ọjọ́ kan mímọ́ fún Olúwa, kì í ṣe ọ̀ṣán, kì í ṣe òru; ṣùgbọ́n yóò ṣe pé, ni àṣálẹ́ ìmọ́lẹ̀ yóò wà.

8 Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, omi ìyè yóò tí Jérúsálẹ́mù ṣàn lọ; ìdájì wọn sìhà òkun ilà-oòrùn, àti ìdájì wọn síhà okùn ẹ̀yìn: nígbà ẹ̀rùn àti nígbà òtútù ni yóò rí bẹ́ẹ̀.

9 Olúwa yóò sì jọba lórí gbogbo ayé; ni ọjọ́ náà ni Olúwa kan yóò wa orúkọ rẹ̀ nìkan náà ni orúkọ.

10 A ó yí gbogbo ilẹ̀ padà bi pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan láti Gébà dé Rímónì lápá gúsù Jérúsálẹ́mù: yóò di bí aginjù, ṣùgbọ́n a ó sì gbé Jérúsálẹ́mù ṣókè, yóò sì gbe ipò rẹ̀, láti ibodè Bẹ́ńjámínì títí dé ibi ibodè èkínní, dé ibodè igun nì, àti láti ile ìṣọ́ Hánánélì dé ibi ìfúńtí wáìnì ọba.