6 Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìmọ́lẹ̀ kì yóò mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ṣókùnkùn.
7 Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ ọjọ́ kan mímọ́ fún Olúwa, kì í ṣe ọ̀ṣán, kì í ṣe òru; ṣùgbọ́n yóò ṣe pé, ni àṣálẹ́ ìmọ́lẹ̀ yóò wà.
8 Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, omi ìyè yóò tí Jérúsálẹ́mù ṣàn lọ; ìdájì wọn sìhà òkun ilà-oòrùn, àti ìdájì wọn síhà okùn ẹ̀yìn: nígbà ẹ̀rùn àti nígbà òtútù ni yóò rí bẹ́ẹ̀.
9 Olúwa yóò sì jọba lórí gbogbo ayé; ni ọjọ́ náà ni Olúwa kan yóò wa orúkọ rẹ̀ nìkan náà ni orúkọ.
10 A ó yí gbogbo ilẹ̀ padà bi pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan láti Gébà dé Rímónì lápá gúsù Jérúsálẹ́mù: yóò di bí aginjù, ṣùgbọ́n a ó sì gbé Jérúsálẹ́mù ṣókè, yóò sì gbe ipò rẹ̀, láti ibodè Bẹ́ńjámínì títí dé ibi ibodè èkínní, dé ibodè igun nì, àti láti ile ìṣọ́ Hánánélì dé ibi ìfúńtí wáìnì ọba.
11 Ènìyàn yóò sì máa gbé ibẹ̀, kì yóò sì sí ìparun mọ́; ṣùgbọ́n a o máa gbé Jérúsálẹ́mù láìléwu.
12 Èyí ni yóò sì jẹ́ àrùn tí Olúwa yóò fi kọlu gbogbo àwọn ènìyàn ti ó tí ba Jérúsálẹ́mù jà; ẹran-ara wọn yóò rù nígbà tí wọn dúró ni ẹṣẹ̀ wọn, ojú wọn yóò sì rà ni ihò wọn, ahọ́n wọn yóò sì bàjẹ́ ni ẹnu wọn.