1 Ó sì fí Jóṣúà olorí àlùfáà hàn mí, ó dúró níwájú ańgẹ́lì Olúwa, Sátanì sí dúró lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti kọjú ìjà sí i.
2 Olúwa si wí fún Sátanì pé, “Olúwa bá ọ wí ìwọ Sátanì; àní Olúwa tí ó ti yan Jérúsálẹ́mù, yóò bá ọ wí, igi inà kọ́ ni èyí tí a mú kúrò nínú iná?”
3 A sì wọ Jóṣúà ni àṣọ èérí, ó sì dúró níwájú ańgẹ́lì náà.
4 Ó sì dáhùn ó wí fún àwọn tí ó dúró níwájú rẹ̀ pé, “Bọ́ aṣọ èérí nì kúrò ní ara rẹ̀.”Ó sì wí fún Jóṣúà pé, “Wòó, mo mú kí àìṣedéédé rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, èmi yóò sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ ẹ̀yẹ.”
5 Mó sì wí pé, “Jẹ kí wọn fi gèlè mímọ́ wé e lórí.” Wọn si fi gèlè mímọ́ wé e lorí, wọn si fi aṣọ wọ̀ ọ́. Ańgẹ́lì Olúwa sì dúró tì í.
6 Ańgẹ́lì Olúwa sì tẹnumọ́ ọn fún Jóṣúà pé:
7 “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Bí ìwọ ọ́ bá rìn ní ọ̀nà mi, bí ìwọ yóò bá sì pa àṣẹ mi mọ́, ìwọ yóò sì ṣe ìdájọ́ ilé mi pẹ̀lú, ìwọ yóò sì ṣe àkóso ààfin mi, èmi yóò fún ọ ní àyè láti rìn láàrin àwọn tí ó dúró yìí.