5 Ańgẹ́lì tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?”Mo sì wí pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n, Olúwa mi.”
6 Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Serubábélì tó wí pé: ‘Kìí ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò se nípa Ẹ̀mí mi,’ ni Olúwa àwọn Ọmọ-ogun wí
7 “Ta ni ìwọ, ìwọ òkè ńlá? Ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú Serubábélì: òun yóò sì fi ariwo mú òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yóò máa kígbe wí pé, ‘Ọlọ́run bùkún-un Ọlọ́run bùkún-un!’ ”
8 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé:
9 “Ọwọ́ Serubábélì ni a ti ṣe ipilẹ̀ ilé yìí, ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì parí rẹ̀; ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí i yín.
10 “Ṣùgbọ́n ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré? Nítorí wọn ó yọ̀ ní, ìwọ̀n lọ́wọ́ Serubábélì.“(Àwọn méje wọ̀nyí ni àwọn ojú Olúwa, tí ó ń sáré síhìn ín sọ́hùn ún ní gbogbo ayé.)”
11 Mo sì béèrè, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn igi ólífì méjì wọ̀nyí jásí, tí ó wà ní apá ọ̀tún fìtílà àti ní apá òsì rẹ̀?”