4 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Arúgbó ọkùnrin, àti arúgbó obìnrin, yóò gbé ìgboro Jérúsálẹ́mù, àti olúkúlùkù pẹ̀lú ọ̀pá ni ọwọ́ rẹ̀ fún ogbó.
5 Ìgboro ìlú yóò sì kún fún ọmọdékùnrin, àti ọmọdé-bìnrin, tí ń ṣiré ní ìta wọn.”
6 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Bí ó bá ṣe ìyanú ní ojú ìyókù àwọn ènìyàn yìí ni ọjọ́ wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó ha lè jẹ́ ìyánú ni ojú mi bí?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
7 Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Kiyesi i, èmi ó gba àwọn ènìyàn mi kúrò ni ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti kúrò ni ilẹ̀ ìwọ̀-oòrùn.
8 Èmi ó sì mú wọn padà wá, wọn ó sì máa gbé àárin Jérúsálẹ́mù: wọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ní òtítọ́, àti ní òdodo.”
9 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Jẹ́ kí ọwọ́ yín le ẹ̀yin ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọjọ́ wọ̀nyí ni ẹnu àwọn wòlíì tí ó wà ni ọjọ́ tí a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun lélẹ̀, jẹ́ ki ọwọ́ rẹ̀ le kí a bá lè kọ́ tẹ́ḿpìlì.
10 Nítorí pé, ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, ọ̀yà ènìyàn kò tó nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀yà ẹran pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àlàáfíà fún ẹni ń jáde lọ, tàbí ẹni ti ń wọlé bọ, nítorí ìpọ́njú náà: nítorí mo dojú gbogbo ènìyàn, olukuluku kọ aládùúgbò rẹ̀.