5 Ásíkélónì yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù;Gásà pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káànú gidigidi,àti Ékírónì: nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò sákì í.Gásà yóò pàdánu ọba rẹ̀,Ásíkélónì yóò sì di ahoro.
6 Ọmọ àlè yóò sì gbé inú Ásídódì,Èmi yóò sì ge ìgbéraga àwọn Fílístínì kúrò.
7 Èmi yóò sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kúrò ni ẹnu rẹ̀,àti àwọn ohun èèwọ̀ kúrò láàrin eyín rẹ̀:ṣùgbọ́n àwọn tó sẹ́kù yóò jẹ́ tí Ọlọ́run wa,wọn yóò sì jẹ baálẹ̀ ní Júdà,àti Ékírónì ni yóò rí bí Jébúṣì.
8 Èmi yóò sì dó yí ilẹ̀ mi kánítorí ogun àwọn tí wọ́n ń wá ohun tí wọn yóò bàjẹ́ kiri,kò sí aninilára tí yóò là wọ́n já mọ́:nítorí ni ìṣinṣin yìí ni mo fi ojú ṣọ́ wọn.
9 Ẹ kún fún ayọ̀, ẹ̀yin ọmọbìnrin ṢíónìẸ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù:Ẹ wo ọba yín ń bọ̀ wá ṣọ́dọ̀ yín:òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà;ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
10 Èmi ó sì gbé kẹ̀kẹ́ kúrò ni Éfúráímù,àti ẹṣin ogun kúrò ni Jérúsálẹ́mù,a ó sì ṣẹ́ ọrun ogun.Òun yóò sì kéde àlàáfíà sí àwọn aláìkọlà.Ìjọba rẹ̀ yóò sì gbilẹ̀ láti òkun dé òkun,àti láti odò títí de òpin ayé.
11 Ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mu mi pẹ̀lú rẹ,Èmi ó dá àwọn ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun.