12 Àwọn ẹni tí a fihàn fún, pé kì í ṣe fún àwọn tìkárawọn bí kò se fún ẹ̀yin, nígba tí wọ́n sọ nípa àwọn ohun tí ẹ ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ń wàásù ìyìnrere náà fún yín nípaṣẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán wá láti ọ̀run.
13 Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀, ẹ kó ara yín ní ìjánu, kí ẹ sì fi ìrètí yín ní kíkún sí ooe-ọ̀fẹ́, èyí tí a ń mu bọ̀ fún yin ni ìgbà ìfarahàn Jésù Kírísítì.
14 Bí àwọn ọmọ tí ń ń gbọ́ràn, láìdá ara yín pọ̀ mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìmọ́ yín ti àtijọ.
15 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o pè yin ti jẹ mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ mímọ́.
16 Nítorí a ti kọ ọ pé, “Ẹ jẹ́ mímọ́: nítorí tí Èmi jẹ mímọ́!”
17 Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti ń képe Baba, ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olúkúlùkù láìṣe ojúsáájú, ẹ máa lo ìgbà àtipó yin ni ìbẹ̀rù.
18 Níwọ̀nbí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín pàdà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín.