9 Ẹ̀yin sì ń gba ìlépa ìgbàgbọ́ yín, àní ìgbàlá ọkàn yín;
10 Ní ti ìgbàlà yìí, àwọn wòlíì tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ tí ó mú tọ̀ yín wá, wádìí jinlẹ̀ jinlẹ̀ pẹ̀lú ìbìkítà tí ó ga jùlọ.
11 Wọ́n ń wádìí ìgbà wo tàbí irú sáà wo ni Ẹ̀mí Kírísítì tí ó wà nínú wọn ń tọ́ka sí, nígbà tí ó jẹ́rìí ìyà Kírísítì àti ògo tí yóò tẹ̀lé e.
12 Àwọn ẹni tí a fihàn fún, pé kì í ṣe fún àwọn tìkárawọn bí kò se fún ẹ̀yin, nígba tí wọ́n sọ nípa àwọn ohun tí ẹ ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ń wàásù ìyìnrere náà fún yín nípaṣẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán wá láti ọ̀run.
13 Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀, ẹ kó ara yín ní ìjánu, kí ẹ sì fi ìrètí yín ní kíkún sí ooe-ọ̀fẹ́, èyí tí a ń mu bọ̀ fún yin ni ìgbà ìfarahàn Jésù Kírísítì.
14 Bí àwọn ọmọ tí ń ń gbọ́ràn, láìdá ara yín pọ̀ mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìmọ́ yín ti àtijọ.
15 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o pè yin ti jẹ mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ mímọ́.