2 Bí ọmọ ọwọ́ titun, kí ẹ máa fẹ́ wàrà ti Ẹ̀mí, èyí tí kò lẹ́tàn, kí ẹ̀yín lè máa tipasẹ̀ rẹ̀ dàgbà sí ìgbàlà.
3 nísinsìnyìí tí ẹ̀yín ti tọ́ ọ wò pé rere ni Olúwa
4 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti tọ̀ ọ́ wá, òkúta ààyè náà, èyí ti àwọn ènìyàn kọ̀ sílẹ̀ ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run yàn, òkúta iyebíye.
5 Ẹ̀yin pẹ̀lú, bí òkúta ààyè, ni a kọ́ ní ilé ẹ̀mí, àlùfáà mímọ́, láti máa rú ẹbọ ẹ̀mí, tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa Jésù Kírísítì.
6 Nítorí nínú ìwé mímọ́, ó wí pe:“Kìyèsi i, mo fi pàtàkì òkúta ìgún-ilẹ̀ àṣàyàn,iyebíye, lélẹ̀ ni Síónì:ẹni tí ó bá sì gbà á gbọ́ojú kì yóò tì í.”
7 Báyìí fún ẹ̀yin ti ẹ gbà á gbọ́, ó ṣe iyebíye; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà á gbọ́,“Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,òun ni ó di pàtàkì ìgún-ilé,”
8 àti pẹ̀lú,“Òkúta ìdìgbòlù,àti àpáta ìkọ̀sẹ̀.”Nítorí wọn kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, sínú èyí tí a gbé yàn wọ́n sí pẹ̀lú.