4 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti tọ̀ ọ́ wá, òkúta ààyè náà, èyí ti àwọn ènìyàn kọ̀ sílẹ̀ ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run yàn, òkúta iyebíye.
5 Ẹ̀yin pẹ̀lú, bí òkúta ààyè, ni a kọ́ ní ilé ẹ̀mí, àlùfáà mímọ́, láti máa rú ẹbọ ẹ̀mí, tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa Jésù Kírísítì.
6 Nítorí nínú ìwé mímọ́, ó wí pe:“Kìyèsi i, mo fi pàtàkì òkúta ìgún-ilẹ̀ àṣàyàn,iyebíye, lélẹ̀ ni Síónì:ẹni tí ó bá sì gbà á gbọ́ojú kì yóò tì í.”
7 Báyìí fún ẹ̀yin ti ẹ gbà á gbọ́, ó ṣe iyebíye; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà á gbọ́,“Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,òun ni ó di pàtàkì ìgún-ilé,”
8 àti pẹ̀lú,“Òkúta ìdìgbòlù,àti àpáta ìkọ̀sẹ̀.”Nítorí wọn kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, sínú èyí tí a gbé yàn wọ́n sí pẹ̀lú.
9 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ìran tí a yàn Olu àlùfáà, Orílẹ̀ èdè mímọ́, ènìyàn ọ̀tọ̀ ki ẹ̀yin lè fi ọla ń lá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn:
10 Ẹ̀yin tí kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ti di ènìyàn Ọlọ́run, ẹ̀yin tí kò rí àánú gbà rí, ṣùgbọ́n nísinsinyìí, ẹ ti rí àánú gbà.