6 Nísìnsinyìí, Tímótíù ti dé pẹ̀lú ìròyìn ayọ̀ wí pé, ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ yín sì lágbára bí i ti àtẹ̀yìnwá. Inú wa dùn láti gbọ́ wí pé ẹ sì ń rántí ìbágbé wa láàrin yín pẹ̀lú ayọ̀. Tímótíù tún fi yé wa pé bí ó ti mú wa lọ́kàn tó láti rí i yín, ni ó ṣe ẹ̀yin pàápàá.
7 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, inú wá dùn jọjọ nínú gbogbo ìyọnu àti ìjìyà wa níbí nítorí pé àwa mọ̀ nísinsinyìí pé, ẹ̀yin sì dúró gbọn-ingbọn-in fún Olúwa.
8 Kò sí nǹkan tí a kò lè fi ara dà níwọ̀n ìgbà tí a ti mọ̀ pé, ẹ̀yin sì dúró gbọn-ingbọn-in fún Olúwa.
9 Kò ṣé é ṣe fún wa láti dá ọpẹ́ tán lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ayọ̀ àti ìfẹ́ tí ó máa ń kún ọkàn wa nípa àdúrà wa fún un yín.
10 Nítorí pé àwa ń gbàdúrà fún un yín lọ̀sán-án àti lóru. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti se àtúnṣe ibi tí ìgbàgbọ́ yín bá kù sí.
11 À ń gbàdúrà wí pé, kí ó wu Ọlọ́run pàápàá àti Olúwa wa Jésù Kírísítì láti rán wa padà sí ọ̀dọ̀ yín lẹ́ẹ̀kan sí í.
12 A sì béérè pé, kí Ọlọ́run ràn yín lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ìfẹ́ yín yóò fi gbòòrò tí yóò sì ṣàn kan olúkúlùkù yín. Èyí yóò jẹ́ àpẹrẹ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ àwa náà se sàn kan ẹ̀yin náà.