2 Oore-ọ̀fẹ́ si yín àti àlàáfíà làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Jésù Kírísítì Olúwa.
3 Olùbùkún ni Ọlọ́run, àti Baba Jésù Kírísítì Olúwa wa, Baba ìyọ́nú, àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo;
4 Ẹni tí ń tù wá nínú ni gbogbo ìdààmú wa, ki àwa lè máa pẹ̀lú tu àwọn tí ó wá nínú ìdààmú nínú, nípá ìtùnú náà ti a fi ń tú àwa fúnra wa nínú làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.
5 Nítorí pé bí ìjìyà Kírísítì ti sínú ayé wa,, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ nì ìtùnú wa dí púpọ pẹ̀lú nípa Kírísítì.
6 Ṣùgbọ́n bí a bá sì ń pọ́n wa lójú, ó jẹ́ fún ìtùnú àti ìgbàlà yín; tàbi bi a bá ń tù wá nínú, ó jẹ́ fún ìtùnú yín ti ń ṣiṣẹ́ sùúrù làti mú yin ní irú ìfaradá ìyà kan náà ti àwa pẹ̀lú ń jẹ́.
7 Àti pé ìrètí wa nípa tiyín dúró ṣinṣin, àwa si mọ̀ pé, bí ẹyin ti jẹ alábápín nínú ìyà wa, bẹ́ẹ̀ ni ẹyin ń pín nínú ìtùnú náà pẹ̀lú.
8 Ará, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè nípa wàhálà tí ó dé bá wa ní agbègbè Éṣíà, ní ti pé a pọ́n wa lójú gidigidi rékọjá agbára ìfaradà wa, tó bẹ́ẹ̀ tí ìrètí kò tilẹ̀ sí fún ẹ̀mí wa mọ́.