12 Ṣùgbọ́n ohun ti mo ń ṣe ni èmi yóò sì máa ṣe, kí èmi lè mú ẹ̀fẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọn ń fẹ́ ṣẹ̀fẹ̀, pé nínú ohun tí wọ́n ṣògo, kí a lè rí wọn gẹ́gẹ́ bí àwa.
13 Nítorí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn èkè Àpósítélì àwọn ẹni ti ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn, tí ń pa wọ́n dà di Àpósítélì Kírísítì.
14 Kì í sì í ṣe ohun ìyanu; nítorí Sátanì, tìkáraarẹ̀ ń pa ara rẹ̀ dà bí ańgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.
15 Nítorí náà kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bá pa ara wọn dà bí àwọn ìrànṣẹ́ òdodo; ìgbẹ́yìn àwọn ẹni tí yóò rí gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.
16 Mo sì tún wí pé, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé òmùgọ̀ ni mí; ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ẹ gbà mí bí òmùgọ̀ kí èmi lè gbé ara mi ga díẹ̀.
17 Ohun tí èmi ń sọ, èmi kò sọ ọ́ nípa ti Olúwa, ṣùgbọ́n bí òmùgọ̀ nínú ìgbẹ́kẹ̀lé ìṣògo yìí.
18 Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ni ó ń ṣògo nípa ti ara, èmi ó ṣògo pẹ̀lú.