19 Nítorí ẹ̀yin fi inú dídùn gba àwọn òmùgọ̀ nígbà tí ẹ̀yin tìkáraayín jẹ́ ọlọgbọ́n.
20 Nítorí ẹ̀yin faradà á bí ẹnìkan bá sọ yín dí òǹdè, bí ẹnìkan bá jẹ́ yín run, bí ẹnìkan bá gbà lọ́wọ́ yín, bí ẹnìkan bá gbé ara rẹ̀ ga, bí ẹnìkan bá gbá yín lójú.
21 Èmi ń wí lọ́nà ẹ̀gàn, bí ẹni pé àwa jẹ́ aláìlera!Ṣùgbọ́n nínú ohunkóhun tí ẹnìkan ti ní ìgboyà, èmi ń sọ̀rọ̀ bí òmùgọ̀, èmi ní ìgboyà pẹ̀lú.
22 Hébérù ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Ísírẹ́lì ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Irú ọmọ Ábúráhámù ní òun bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi.
23 Iránṣẹ́ Kírísítì ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọpọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbákùúgbà, ní ti fífẹ́rẹ̀ kú nígbà púpọ̀.
24 Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín kan lọ́wọ́ àwọn Júù.
25 Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kanṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú.