1 Èmi kò lè sàì sògo bí kò tilẹ̀ ve àǹfààní, nítorí èmi ó wà sọ nípa ìran àti ìṣípayá ti Olúwa fihàn mí.
2 Èmi mọ ọkùnrin kan nínú Kírísítì ní ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yin, yálà nínú ara ni, èmi kò mọ̀; tàbí kúrò nínú ara, èmi kò mọ̀; Ọlọ́run mọ̀: a gbé irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ lọ sí ọ̀run kẹta.
3 Bẹ́ẹ̀ ni èmi mọ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀, yálà ní ara ni, tàbí kúrò nínú ara ni, èmi kò mọ̀: Ọlọ́run mọ̀.
4 Pé a gbé e lọ sókè sí Párádísè, tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí a kò sì lè sọ, tí kò tọ́ fún ènìyàn láti máa sọ.
5 Nípa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni èmi ó máa ṣògo: ṣùgbọ́n nípa ti èmi tìkáraami èmi kì yóò ṣògo, bí kò ṣe nínú àìlera mi.
6 Nítorí pé bi èmi tilẹ̀ ń fẹ́ máa ṣògo, èmi kì yóò jẹ́ òmùgọ̀; nítorí pé èmi yóò sọ òtítọ́: ṣùgbọ́n mo kọ̀, kí ẹnikẹ́ni máa bà à fi mí pè ju ohun tí ó rí tí èmi jẹ́ lọ, tàbí ju èyí tí ó gbọ́ lẹ́nu mi.