10 Nítorí náà èmi ní inú dídùn nínú àìlera gbogbo, nínú ẹ̀gàn gbogbo, nínú àìní gbogbo, nínú inúníbíni gbogbo, nínú wàhálà gbogbo nítorí Kírísítì. Nítorí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.
11 Mo di òmùgọ̀ nípa ṣíṣògo; ẹ̀yin ní ó fí ipá mú mi ṣe é: nítorí tí ó tọ́ tí ẹ bá yìn mí: nítorí tí èmi kò rẹ̀yìn lóhunkóhun sí àwọn àgbà Àpósítélì bí èmi kò tilẹ̀ jámọ́ nǹkan kan.
12 Ohun kan tí ó ṣe àmì àpósítélì, iṣẹ́ ìyanu and iṣẹ́ agbára ní won ṣe ní àárin yín pẹ̀lú sùúrù tó ga.
13 Nítorí nínú kín ni ohun tí ẹ̀yin ṣe rẹ̀yìn sí ìjọ mìíràn, bí kò ṣe ní ti pé èmi fúnra mi kó jẹ́ oníyọnú fún yín? Ẹ dárí àṣìṣe yìí jì mí.
14 Kíyèsí i, ìgbà kẹta yìí ni mo múra tan láti tọ̀ yín wá: èmi kì yóò sì jẹ́ oníyọnu fún yín nítorí tí èmi kò wá nǹkan yín, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnra yín; nítorí tí kò tọ́ fún àwọn ọmọ láti máa to ìṣúra jọ fún àwọn òbí wọn, bí kò se àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn.
15 Èmi ó sì fi ayọ̀ ná ohun gbogbo tí mo bá ní, èmi ó sì ná ara mi fún ọkàn yín nítòótọ́; bí mo bá fẹ́ yín lọ́pọ̀lọpọ̀, ó há tọ́ kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn mi díẹ̀ bí?
16 Ṣùgbọ́n ó dára bẹ́ẹ̀ tí èmi kò dẹ́rúbà yín: ṣùgbọ́n bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, èmi ń fí ọwọ́ ẹ̀rọ̀ mú yín.