10 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá dáríjín ẹnikẹ́ni, èmí fi jì pẹ̀lú. Èmi ti dárìjìn níwájú Kírítí nítorí yín.
11 Kí Sàtánì má baà rẹ́ wa jẹ. Nítorí àwa kò ṣe aláìmọ́ àrékérekè rẹ̀.
12 Ṣùgbọ́n nígbá ti mo dé Tíróà láti wàásù iyinrere Kírísitì, tí mo sì ríi wí pé Olúwa ti sílẹ̀kùn fún mi,
13 Síbẹ̀ èmi kò ní àlàáfíà lọ́kan mi, nítorí tí èmi kò rí Títù arákùnrin mi níbẹ̀. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe dágbére fún wọn, mo si rékọjá lọ sí Makedóníà,
14 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹni tí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí wá nígbà gbogbo nínú Kírísítì, tí a sì ń fi òórùn ìmọ̀ rẹ̀ hàn nípa wa níbi gbogbo.
15 Nítorí òórùn dídùn Kírísítì ni àwa jẹ́ fún Ọlọ́run, nínú àwọn tí a ń gbàlà àti nínú àwọn tí ó ń ṣègbé:
16 Fún àwọn kan, àwa jẹ́ òórùn ikú sí ikú, àti fún àwọn mìíràn òórùn ìyè sí ìyè. Ta ni ó há si tọ́ fún nǹkan wọ̀nyí?