13 Síbẹ̀ èmi kò ní àlàáfíà lọ́kan mi, nítorí tí èmi kò rí Títù arákùnrin mi níbẹ̀. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe dágbére fún wọn, mo si rékọjá lọ sí Makedóníà,
14 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹni tí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí wá nígbà gbogbo nínú Kírísítì, tí a sì ń fi òórùn ìmọ̀ rẹ̀ hàn nípa wa níbi gbogbo.
15 Nítorí òórùn dídùn Kírísítì ni àwa jẹ́ fún Ọlọ́run, nínú àwọn tí a ń gbàlà àti nínú àwọn tí ó ń ṣègbé:
16 Fún àwọn kan, àwa jẹ́ òórùn ikú sí ikú, àti fún àwọn mìíràn òórùn ìyè sí ìyè. Ta ni ó há si tọ́ fún nǹkan wọ̀nyí?
17 Nítorí àwa kò dàbí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí ń fí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣòwò jẹun; ṣùgbọ́n nínú òtítọ́ inú àwa ń sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọ́run nínú Kírísítì gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.