11 Nítorí náà bí àwa ti mọ ẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí ènìyàn lọ́kàn padà; ṣùgbọ́n a ń fí wá hàn fún Ọlọ́run; mo sì gbàgbọ́ pé, a sì ti fì wá hán ní ọkàn yín pẹ̀lú.
12 Nítorí àwa kò sì ní máa tún yin ara wá sí i yín mọ́, ṣùgbọ́n àwa fi ààyè fún yín láti máa ṣògo nítorí wa, kí ẹ lè ní ohun tí ẹ̀yin yóò fi dá wọn lóhùn, àwọn ti ń ṣògo lodé ara kì í ṣe ní ọkàn.
13 Nítorí náà bí àwa bá ń sínwín, fún Ọlọ́run ni: tàbí bí iyè wá bá sí pépé, fún yín ni.
14 Nítorí ifẹ́ Kírísítì ń rọ̀ wá, nítorí àwa mọ̀ báyìí pé, bí ẹnìkan bá kú fún gbogbo ènìyàn, ǹjẹ́ nígbà náà, gbogbo wọ́n ni ó ti kú.
15 Ó sì ti kú fún gbogbo wọn, pé kí àwọn tí ó wà láàyè má sì ṣe wà láàyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí wọn, tí ó sì ti jíǹde.
16 Nítorí náà láti ìṣinṣin yìí lọ, àwa kò mọ ẹnìkan nípa ti ara mọ́; bí àwa tilẹ̀ ti mọ Kírísítì nípa ti ara, ṣùgbọ́n níṣinṣin yìí àwa kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́.
17 Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kírísítì, ó di ẹ̀dá titun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsí i, ohun titun ti dé.