10 Nítorí pé ìbànújẹ́ ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run a máa ṣiṣẹ́ ìrònúpìwadà sí ìgbàlà tí kì í mú àbámọ̀ wá: ṣùgbọ́n ìbànújẹ́ ti ayé a máa ṣiṣẹ́ ikú.
11 Kíyèsí i, nítorí ohun kan náà yìí tí a mú yin banújẹ́ fún bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, irú ìmúrá-ṣíṣẹ́ tí ó mú jáde nínú yín, wíwẹ ara yín mọ́ ńkọ́ ìbànújẹ́ ńkọ́, ìpayà ńkọ́, ìfojúsọnà ńkọ́, ìtara ńkọ́, ìjẹ́ni-níyà ńkọ́. Nínú ohun àmì kọ̀ọ̀kan yìí ni ẹ̀yin ti fi ara yín hàn bí aláìlẹ́bi nínú ọ̀ràn náà.
12 Nítorí náà, bí mo tilẹ̀ tí kọ̀wé sí yín, èmi kò kọ ọ́ nítorí ẹni tí ó ṣe ohun búburú náà tàbí nítorí ẹni ti a fi ohun búburú náà ṣe, ṣùgbọ́n kí àníyàn yín nítorí wá lè farahàn níwájú Ọlọ́run.
13 Nítorí náà, a tí fí ìtùnú yín tù wá nínú.Àti nínú ìtùnú wa, a yọ̀ gidigidi nítorí pé Títù ní ayọ̀, nítorí láti ọ̀dọ̀ gbogbo yín ni a ti tu ẹ̀mí rẹ̀ lára.
14 Bí mo tilẹ̀ ti lérí ohunkóhun fún ún nítorí yín, a kò dójú tì mí; ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwa ti sọ ohun gbogbo fún yín ní òtítọ́, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ìlérí wá níwájú Títù sì já sí òtítọ́.
15 Ọkàn rẹ̀ sì fà gidigidi sí yín, bí òun ti ń ránti ìgbọ́ràn gbogbo yín, bí ẹ ti fi ìbẹ̀rù àti ìwárìrì tẹ́wọ́gbà á.
16 Mo yọ̀ nítorí pé ní ohun gbogbo, mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú yín.