13 Ohun tí ó gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi, pa a mọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ rere nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ Kírísítì Jésù.
14 Pa ohun rere ti a ti fi lé ọ lọ́wọ́ mọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ti ń gbé inú wa.
15 Èyí ni ìwọ mọ̀ pé, gbogbo àwọn ti ó wà ni agbègbè Ésíà ti fí mí sílẹ̀, nínú àwọn ẹni tí Fígélíù àti Hámógénè gbé wà.
16 Kí Olúwa fi àánú fún ilé Ònésífórù; nítorí ti ó máa ń tù mi lára nígbà púpọ̀, ẹ̀wọ̀n mi kò sì tì í lójú.
17 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wà ni Rómù, ó fi ẹ̀sọ̀ wá mi, ó sì rí mi.
18 Kí Olúwa fi fún un kí ó lè rí àánú lọ́dọ̀ Olúwa ni ọjọ́ náà! Ìwọ tìkararẹ sáà mọ̀ ọ̀nà gbogbo tí ó gbà rànmí lọ́wọ́ ni Éfésù.