Éfésù 2 BMY

Ìsọdààyè nínú Kírísítì

1 Ní ti ẹ̀yin, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè, nígbà ti ẹ̀yin ti kú nítorí ìrékọjá àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín,

2 nínú èyí tí ẹ̀yin ti gbé rí àní bí ipá ti ayé yìí, gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ agbára ojú ọ̀run, ẹ̀mí tí n ṣiṣẹ́ ni isinsìn yìí nínú àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn.

3 Nínú àwọn ẹni tí gbogbo wa pẹ̀lú ti wà rí nínú ìfẹ́kúfẹ ara wa, a ń mú ìfẹ́ ara àti ti inú ṣẹ, àti nípa ẹ̀dá àwa sì ti jẹ́ ọmọ ìbínú, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìyókù pẹ̀lú.

4 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run, ẹni tí í ṣe ọlọ́rọ̀ ni àánú, nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó fi fẹ́ wa,

5 nígbà tí àwa tilẹ̀ ti kú nítorí ìrékọjá wa, ó sọ wá di ààyè pẹ̀lú Kírísítì oore ọ̀fẹ́ ni a ti fi gbà yín là.

6 Ọlọ́run sì ti jí wa dìde pẹ̀lú Kírísítì, ó sì ti mú wa jókòó pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run nínú Kírísítì Jésù.

7 Pé ni gbogbo ìgbà tí ń bọ̀ kí ó bà á lè fi ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí o pọ̀ rékọjá hàn fún wa nínú ìṣehun rẹ̀ sì wà nínú Kírísítì Jésù.

8 Nítorí oore ọ̀fẹ́ ní a fi gbà yín là nípa ìgbàgbọ́: àti èyí yìí kì í ṣe ti láti ọ́dọ̀ ẹ̀yin fúnra yín: ẹ̀bùn Ọlọ́run ni:

9 Kì í ṣe nípa àwọn iṣẹ́, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣògo.

10 Nítorí àwa ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tí a ti dá nínú Kírísítì Jésù fún àwọn iṣẹ́ rere, èyí tí Ọlọ́run ti pèṣè tẹ́lẹ̀, fún wa láti ṣe.

Ọ̀kan Nínú Kírísítì

11 Nítorí náà ẹ rántí pé, nígbà àtijọ́ rí, ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ aláìkọlà nípa ti ìbí, tí àwọn tí a ń pè ní Akọlà ti a fi ọwọ́ ṣe ni ara ń pè ní Aláìkọlà.

12 ẹ rántí pé ni àkókò náà ẹ̀yin wà láìní Kírísítì, ẹ jẹ́ àjèjì sí àǹfàní àwọn ọlọ̀tọ̀ Ísírẹ́lì, àti àlejò sí àwọn májẹ̀mú ìlérí náà, láìní ìrètí, àti láìní Ọlọ́run ni ayé:

13 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nínú Kírísítì Jésù ẹ̀yin tí ó ti jìnà réré nígbà àtijọ́ rí ni a mú súnmọ́ tòsí, nípa ẹ̀jẹ̀ Kírísítì.

14 Nítorí oun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórira èyí tí ń bẹ láàrin yín.

15 Nípa pípa àṣẹ, àwọn òfin àti ìlànà gbogbo rẹ̀ nínú ara rẹ̀. Àfojúsùn rẹ̀ i kí ó le dá ọkùnrin tuntun kan nínú ara rẹ̀ nínú àwọn méjèèjì, kí àlááfíà kí ó lè wà nípa èyí.

16 àti kí ó lè mú àwọn méjèèjì bá Ọlọ́run làjà nínú ara kan nípa àgbélébùú; nípa èyí tí yóò fi pa ìsòtá náà run.

17 Ó sì ti wá ó sì ti wàásù àlàáfíà fún ẹ̀yin tí o jìnnà réré, àti àlááfíà fún àwọn tí o súnmọ́ tòòsí.

18 Nítorí nípa rẹ̀ ni àwa méjèèjì ti ni àǹfààní sọ́dọ̀ baba nípa Ẹ̀mí kan.

19 Ǹjẹ́ nítorí náà ẹ̀yin kì í ṣe àlejò àti àtìpó mọ́, ṣùgbọ́n àjùmọ̀jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn ara ilé Ọlọ́run;

20 a sì ń gbé yín ró lórí ìpilẹ̀ àwọn àpostélì, àti àwọn wòlíì, pẹ̀lú Jésù Kírísítì fúnra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí pàtàkì òkúta igun ilé;

21 Nínú rẹ ni gbogbo ilé náà, tí a ń kọ wà papọ̀ sọ̀kan tí ó sì ń dàgbà sókè láti di tẹ́ḿpìlì mímọ́ kan nínú Olúwa:

22 Nínú rẹ̀ ni a ń gbé ẹ̀yin pẹ̀lú ró pọ̀ pẹ̀lú fún ibùjókòó Ọlọ́run nínú Ẹ̀mí rẹ̀.

orí

1 2 3 4