Éfésù 3 BMY

Pọ́ọ̀lù Jẹ́ Oníwàásù Sí Àwọn aláìkọlà.

1 Nítorí èyí náà ni èmi Pọ́ọ̀lù ṣe di òǹdè Jésù Kírísítì nítorí ẹ̀yin aláìkọlà,

2 Bí ẹ̀yin bá tilẹ̀ ti gbọ́ ti iṣẹ́ ìríjú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, tí a fifún mi fún yín;

3 Bí ó ti ṣe pé nípa ìfihàn ni ó ti fi ohun ìjìnlẹ̀ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ṣáájú ni sókí,

4 Nígbà tí ẹ̀yin bá kà á, nípa èyí tí ẹ̀yin o fi lè mọ òye mi nínú ìjìnlẹ̀ Kírísítì.

5 Èyí tí a kò í tíì fihàn àwọn ọmọ ènìyàn rí nínú ìran mìíràn gbogbo, bí a ti fi wọ́n hàn nísinsin yìí fún àwọn àpostélì rẹ̀ mímọ́ àti àwọn wòlíì nípa Ẹ̀mí;

6 Pé, àwọn aláìkọlà jẹ́ àjùmọ̀jogún àti ẹ̀yà ara kan náà, àti alábápín ìlérí nínú Kírísítì Jésù nípa ìyìn rere;

7 Ìránṣẹ èyí tí a fi mi ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fifún mi, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀.

8 Fún èmi tí o kéré jùlọ nínú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ní a fi oore ọ̀fẹ́ yìí fún, láti wàásù àwámárídi ọ̀rọ̀ Kírísítì fún àwọn aláìkọlà;

9 Àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ayébáyé nínú Ọlọ́run, ẹni tí o dá ohun gbogbo nípa Jésù Kírísítì:

10 Kí a bà á lè fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ onirúuru ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nísinsin yìí fún àwọn ìjòyè àti àwọn alágbára nínú àwọn ọ̀run, nípasẹ̀ ìjọ,

11 gẹ́gẹ́ bí ìpinnu àtayébáyé tí ó ti pinnu nínú Kírísítì Jésù Olúwa wa:

12 Nínú ẹni tí àwa ní ìgboyà, àti ọ̀nà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀.

13 Nítorí náà mo bẹ̀ yín kí àárẹ̀ má ṣe mú yín ni gbogbo wàhálà mi nítorí yín, tíi ṣe ògo yín.

Àdúrà Fún Àwọn Ará Éfésù

14 Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eekún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jésù Kírísítì.

15 Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé.

16 Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ mú ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.

17 Kí Kírísítì lè máa gbé inú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́; pé bí ẹ ti ń fi gbòǹgbò múlẹ̀ tí ẹ sì ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́;

18 Kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga náàìfẹ́ Kírísítì jẹ́.

19 Àti láti mọ̀ ìfẹ́ Kírísitì yìí tí o ta ìmọ̀ yọ, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kún Ọlọ́run kún yín.

20 Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa.

21 Òun ni kí a máa fi ògo fún nínú ìjọ àti nínú Kírísítì Jésù títí ìrandíran gbogbo, ayé àìnípẹ̀kun, Àmí.

orí

1 2 3 4