Éfésù 1 BMY

1 Pọ́ọ̀lù, Àpósítélì Jésù Kírísítì nípa ìfẹ́ Ọlọ́run,Sí àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní Éfésù, àti sí àwọn olótìtọ́ nínú Kírísíti Jésù:

2 Oore ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jésù Kírísítì Olúwa.

Ìbùkún Ti Ẹ̀mí Mímọ́ Nínú Kírísítì

3 Ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba Jésù Kírísítì Olúwa wa, ẹni tí ó ti bùkún wa láti inú ọ̀run wá pẹ̀lú àwọn ìbùkún ẹ̀mí gbogbo nínú Kírísítì.

4 Àní, gẹ́gẹ́ bí o ti yàn wá nínú rẹ̀ ṣáájú ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀. Nínú ìfẹ́

5 ni Ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ sí ìsọdọmọ nípa Jésù Kírísítì fún ara rẹ̀, ní ìbámu ìdùnnú ìfẹ́ rẹ̀

6 fún ìyìn ogo oore ọ̀fẹ́ rẹ̀, èyí tí Ó ti fi fún wa nínú Àyànfẹ́ rẹ̀:

7 Nínú rẹ̀ ni àwa ni ìràpadà wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run

8 èyí tí ó ya lù wá pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti ìmòye,

9 Ó ti sọ ohun ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mímọ̀ fún wa, gẹ́gẹ́ bí idùnnù rere rẹ̀, èyí ti o pinnu nínú Kírísítì,

10 èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ orí kan àní Kírísítì.

11 Nínú rẹ̀ ni a yàn wá fẹ́ lẹ́hìn tí ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinu ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní ìbámu ìfẹ́ rẹ̀,

12 kí àwa tí ó jẹ́ àkóso ìrètí nínú Kírísítì lè jásí ìyìn ògo rẹ̀.

13 Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kírísítì nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìyìnrere ìgbàlà yin. Lẹ́yìn tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a lù yín ní òǹtẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀,

14 èyí tí ó jẹ́ ìdánilójú àsansílẹ̀ ogún wa títí yóò fi di àkókò ìràpadà àwọn tí í ṣe ìní Ọlọ́run sí ìyìn ògo rẹ̀.

Àwọn Ìdúpẹ́ Àti Àdúrà

15 Nítorí ìdí èyí, nígbà tí mo ti gbúro ìgbàgbọ́ ti ń bẹ láàárin yín nínú Jésù Olúwa, àti ìfẹ́ yín sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.

16 Èmi kò sì sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, àti láti máa rántí yín nínú àdúrà mi;

17 Mo sì ń bèèrè nígbàgbogbo pé kí Ọlọ́run Jésù Kírísítì Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọ̀gbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ọ́ sí i.

18 Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkan yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìreti ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́.

19 àti aláìlẹ́gbẹ́ títóbi agbára rẹ̀ fún àwa tí a gbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ agbára rẹ̀,

20 èyí tí ó fi sínú Kírísítì, nígbà tí o ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì mú un jòkòó lọ́wọ́ ọ̀tún nínú àwọn ọ̀run.

21 Ó gbé e ga ju gbogbo ìsàkóso, àti àṣẹ, àti agbára, àti ilẹ̀ ọba àti gbogbo àpèlé orúkọ tí a lè ti fún mi, kì í ṣe ni ayé yìí nìkan, ṣùgbọ́n ni èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú.

22 Ọlọ́run sì ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ.

23 èyí tí i ṣe ara rẹ̀, ẹ̀kún ẹni tí o kún ohun gbogbo ní gbogbo ọ̀nà.

orí

1 2 3 4