22 Pé, ní tì ìwà yín àtijọ́, kí ẹ̀yin bọ́ ogbologbo ọkùnrin nì sílẹ̀, èyí tí ó díbàjẹ́ gẹ́gẹ̀ bí ìfẹ́kúfẹ́ ẹ̀tàn;
23 Kí ẹ sì di titun ni ẹ̀mí inú yín;
24 Kí ẹ sì gbé ọkùnrin titun wọ̀, èyí tí a dá ni àwòrán Ọlọ́run nínú òdodo àti ìwà mímọ́ ti òtítọ́.
25 Nítorí náà ẹ fi èké ṣiṣe sílẹ̀, ki olúkúlùkù yín máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara ọmọnìkejì wa ni àwá jẹ́.
26 Nínú ìbínú yín, ẹ máa ṣe ṣẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kí òòrùn wọ̀ bá ìbínú yín:
27 Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè fún Èṣù.
28 Kí ẹni tí ń jalè má ṣe jalè mọ́: ṣùgbọ́n kí ó kúkú máa ṣe làálàá, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ ohun tí ó dara, kí òun lè ní láti pín fún ẹni tí ó ṣe aláìní.