28 Kí ẹni tí ń jalè má ṣe jalè mọ́: ṣùgbọ́n kí ó kúkú máa ṣe làálàá, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ ohun tí ó dara, kí òun lè ní láti pín fún ẹni tí ó ṣe aláìní.
29 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìdibàjẹ́ kan ti ẹnu yín jáde, ṣùgbọ́n irú èyí ti o dara fún ẹ̀kọ́, kí ó lè máa fi oore ọ̀fẹ́ fún àwọn tí ń gbọ́.
30 Ẹ má sì ṣe mú Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run bínú, ẹni tí a fi ṣe èdìdì yín dé ọjọ́ ìdáǹdè.
31 Gbogbo ìwà kíkorò àti ìbínú, àti ìrunú, àti ariwo, àti ọ̀rọ̀ búburú ni kí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, pẹ̀lú gbogbo àránkan:
32 Ẹ máa ṣoore fún ọmọnìkéjì yín, ẹ ní ìyọ́nú, ẹ máa dáríji ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run nínú Kírísítì ti dáríjì yín.