Jákọ́bù 1 BMY

1 Jákọ́bù, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti ti Jésù Kírísítì Olúwa,Sí àwọn ẹ̀yà méjìlá tí ó fọ́n káà kiri, orílẹ̀-èdè.Àlàáfíà.

Àwọn Ìṣòro Àti Àwọn Ìdẹwò

2 Ẹ̀yin ara mi, nígbà tí ẹ̀yin bá bọ́ sínú onírúurú ìdẹwo ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀;

3 Nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ pé, ìdẹwò ìgbàgbọ́ yín ń ṣisẹ́ sùúrù.

4 Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí sùúrù kí ó ṣiṣẹ́ àṣepé, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ́ pípé àti aláìlábùkù tí kò se aláìní ohunkóhun.

5 Bí ó bá ku ọgbọ́n fún ẹnikẹ́ni, kí ó béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ẹni tí fi fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí kì í sì ka àlébù sí; a ó sì fi fún un.

6 Ṣùgbọ́n nígbà tí òun bá bèèrè ní ìgbàgbọ́, ní àìṣiyèméjì rárá. Nítorí ẹni tí ó ń sé iyè méjì dàbí ìgbì omi òkun, tí à ń ti ọwọ́ afẹ́fẹ́ bì síwá bì sẹ́yìn, tí a sì ń rú u sókè.

7 Kí irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ má ṣe rò pé, òun yóò rí ohunkóhun gbà lọ́wọ́ Olúwa;

8 Ó jẹ ènìyàn oníyèméjì aláìllèdúró ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo.

9 Ṣùgbọ́n jẹ́ kí arákùnrin tí ó ń ṣe onírẹ̀lẹ̀ máa ṣògo ní ipò gíga.

10 Àti ọlọ́rọ̀, ní ìrẹ̀sílẹ̀, nítorí bí ìtànná koríko ni yóò kọjá lọ.

11 Nítorí oòrùn là ti òun ti ooru mímú ó sì gbẹ́ koríko, ìtànná rẹ̀ sì rẹ̀ dànú, ẹwà ojú rẹ̀ sì parun: bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ọlọ́rọ̀ yóò ṣègbé ní ọ̀nà rẹ̀.

12 Ìbùkún ni fún ọkùnrin tí ó fi ọkàn rán ìdẹwò; nítorí nígbà tí ó bá yege, yóò gba adé ìyè, tí Olúwa ti ṣèlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ.

13 Kí ẹnikẹ́ni tí a dẹwò kí ó má ṣe wí pé, “Láti ọwọ́ Ọlọ́run ni a ti dán mi wò.” Nítorí a kò lè fi búburú dán Ọlọ́run wò, òun náà kì í sì í dán ẹnìkẹ́ni wò;

14 Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni a ń dánwò nígbà tí a bá fi ọwọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara rẹ̀ fà á lọ tí a sì tàn án jẹ.

15 Ǹjẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nígbà tí ó bá lóyún a bí ẹ̀ṣẹ̀, àti ẹ̀ṣẹ̀ náà nígbà tí ó bá dàgbà tán a bí ikú.

16 Kí a má ṣe tàn yín jẹ, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́.

17 Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà.

18 Ó pinnu láti fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa kí àwa kí ó le jẹ́ àkọ́so nínú ohun gbogbo tí ó dá.

Gbígbọ́ Àti Ṣíṣe Ọ̀rọ̀ Náà

19 Kí ẹmọ èyí, ẹ̀yin ara mi olùfẹ́; jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa yára láti gbọ́, kí ó lọ́ra láti fọhùn kí ó si lọ́ra láti bínú;

20 Nítorí ìbínú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ òdodo irú èyí tí Ọlọ́run ń fẹ́.

21 Nítorí náà, ẹ lépa láti borí gbogbo èérí àti ìwà búburútí ó gbilẹ̀ yíka, kí ẹ sì fi ọkàn tútù gba ọ̀rọ̀ náà tí a gbìn, tí ó lè gba ọkàn yín là.

22 Ẹ maa kan jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rà náà lásán, kí ẹ má baà tipa èyí tan ara yín jẹ́. Ẹ ṣse ohun tí ó sọ.

23 Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí kò sì jẹ́ olùṣe, òun dàbí ọkùnrin tí ó ń ṣàkíyèsí ojú ara rẹ̀ nínú díńgí

24 Nítorí, lẹ́yìn tí ó bá ti sàkíyèsí ara rẹ̀, tí ó sì bá tirẹ̀ lọ, lójú kan náà òun sì gbàgbé bí òun ti rí.

25 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé, òfin òmìnira ni, tí ó sì dúró nínú rẹ̀, tí òun kò sì jẹ́ olùgbọ́ tí ń gbàgbé bí kò ṣe olùṣe rẹ̀, òun yóò jẹ́ alábùkún nínú iṣẹ́ rẹ̀.

26 Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń sin Ọlọ́run nígbà tí kò kó ahọ́n rẹ̀ ní ìjánu, ó ń tan ọkàn ara rẹ̀ jẹ, ìsìn rẹ̀ sì jẹ́ asán.

27 Ìsìn mímọ́ àti aláìléèérí níwájú Ọlọ́run àti baba ni èyí, láti máa bojú tó àwọn aláìní-baba àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara rẹ̀ mọ́ láì lábàwọ́n kúrò nínú ayé.

orí

1 2 3 4 5