1 Ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́ nínú ògo Olúwa wá Jésù Kírísítì, ẹ máa ṣe ojúsàájú ẹnikẹ́ni.
2 Nítorí bí ọkùnrin kan bá wá sí ìpéjọpọ̀ yín, pẹ̀lú òrùka wúrà àti aṣọ dáradára, tí talákà kan sì wá pẹ̀lú nínú aṣọ èérí;
3 Tí ẹ̀yin sì bu ọla fún ẹni tí ó wọ aṣọ dáradára tí ẹ sì wí pé, “Ìwọ jókòó níhìn-ín yìí ní ibi dáradára” tí ẹ sì wí fún talákà náà pé, “Ìwọ dúró níbẹ̀” tàbí “jókòó níhìn-ín lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi;”
4 Ẹ̀yin kò ha ń dá ara yín sí méjì nínú ara yín, ẹ̀yin kò sì di onídàájọ́ tí ó ní èrò búburú bí?
5 Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́: Ọlọ́run kò ha ti yan àwọn talákà ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́, àti ajogún ìjọba náà, tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ?
6 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti bu talákà kù. Àwọn ọlọ́rọ̀ kò ha ń pọ́n ẹ̀yin lójú bí; wọn kò ha sì ń wọ́ yín lọ sílé ẹjọ́?
7 Wọn kò ha ń sọ ọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ rere nì tí a fi ń pè yín bí?
8 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń mú olú òfin nì ṣẹ gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́, èyí tí ó wí pé, “Ìwọ fẹ́ ẹni kejì rẹ bí ara rẹ,” ẹ̀yin ń ṣe dáradára.
9 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ń ṣe ojúsáájú ènìyàn, ẹ̀yin ń dẹ́ṣẹ̀, a sì ń dá yín lẹ́bi nípa òfin bí arúfin.
10 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa gbogbo òfin mọ́, tí ó sì rú ọ̀kan, ó jẹ̀bi rírú gbogbo rẹ̀.
11 Nítorí ẹni tí ó wí pé, “Má ṣe ṣe panṣágà,” òun ni ó sì wí pé, “Má ṣe pànìyàn.” Ǹjẹ́ bí ìwọ kò ṣe panṣágà, ṣùgbọ́n tí ìwọ pànìyàn, ìwọ jásí arúfin.
12 Ẹ máa sọ̀rọ̀, ẹ sì máa hùwà, bí àwọn tí a ó fi òfin òmìnira dá lẹ́jọ́.
13 Nítorí ẹni tí kò ṣàánú, ni a ó ṣe ìdájọ́ fún láìsí àánú; àánú ń ṣògo lórí ìdájọ́.
14 Èrè kí ni ó jẹ́, ará mi, bí ẹni kan wí pé òun ní ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí kò ní àwọn iṣẹ́? Ìgbàgbọ́ náà lè gbà á là bí?
15 Bí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá wà ní àìní aṣọ, tí ó sì ṣe àìní oúnjẹ òòjọ́,
16 Tí ẹni kan nínú yín sì wí fún pé, “máa lọ ní àlàáfíà, kí ara rẹ kí ó má ṣe tutù, kí ó sì yó,” ṣùgbọ́n ẹ kò fi nǹkan wọ̀n-ọn-nì ti ara ń fẹ́ fún wọn; èrè kí ni ó jẹ́?
17 Bẹ́ẹ̀ sì ni ìgbàgbọ́, bí kò bá ní iṣẹ́ rere, ó kú nínú ara rẹ̀.
18 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni lè wí pé, “Ìwọ ní ìgbàgbọ́, èmi sì ní iṣẹ́:”Fi ìgbàgbọ́ rẹ hàn mí ní àìsí iṣẹ́, èmi ó sì fi ìgbàgbọ́ mi hàn ọ́ nípa iṣẹ́ rere mi.
19 Ìwọ gbàgbọ́ pé Ọlọ́run kan ní ó ń bẹ; ó dára! Àwọn ẹ̀mí èṣù pẹ̀lú gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì wá rìrì.
20 Ṣùgbọ́n, ìwọ aláìmòye ènìyàn, ìwọ ha fẹ́ ní ìdánilójú pé, ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ rere asán ni?
21 Kí ha í ṣe nípa iṣẹ́ ni a dá Ábúrámù baba wa láre, nígbà tí ó fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rúbọ lórí pẹpẹ?
22 Ìwọ rí i pé ìgbàgbọ́ rẹ bá iṣẹ́ rìn, àti pé nípa iṣẹ́ rere ni a sọ ìgbàgbọ́ di pípé.
23 Ìwé mímọ́ sì ṣẹ́ tí ó wí pé, “Ábúrámù gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un,” a sì pè é ní ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.
24 Ǹjẹ́ ẹ̀yin rí i pé nípa iṣẹ́ rere ni à ń dá ènìyàn láre, kì í ṣe nípa ìgbàgbọ́ nìkan.
25 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú kí a dá Ráhábù panṣágà láre nípa iṣẹ́ bí, nígbà tí ó gba àwọn amí, tí ó sì rán wọn jáde gba ọ̀nà mìíràn?
26 Nítorí bí ara ní àìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ ní àìsí iṣẹ́ jẹ́ òkú.