Jákọ́bù 5 BMY

Ìkìlọ̀ Fún Àwọn Aninilára Ọlọ́rọ̀

1 Ẹ wá nísinsìn yìí, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀, ẹ máa sọkún kí ẹ sì máa pohùn réré ẹkún nítorí òsì tí ó ń bọ̀ wá ta yín.

2 Ọrọ̀ yín díbàjẹ́, kòkòrò sì ti jẹ aṣọ yín.

3 Góòlù òun sílífà yín díbàjẹ́; ìbàjẹ́ wọn ni yóò sì ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, tí yóò sì jẹ ẹran ara yín bí iná. Ẹ̀yin tí kó ìsúra jọ de ọjọ́ ìkẹyìn.

4 Kíyè sí i, ọ̀yà àwọn alágbàṣe tí wọ́n ti ṣe ìkórè oko yín, èyí tí ẹ kò san, ń ké rara; àti igbe àwọn tí ó ṣe ìkórè sì ti wọ inú etí Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

5 Ẹ̀yin ti jẹ adùn ní ayé, ẹ̀yin sì ti fi ara yín fún ayé jíjẹ; ẹ̀yin ti mú ara yín sanra de ọjọ́ pípa.

6 Ẹ̀yin ti dá ẹ̀bi fún olódodo, ẹ sì ti pa á; òun kò kọ ojú ijà sí yín.

Sùúrù Nínú Ìjìyà

7 Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadàwá Olúwa. Kíyèsí i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò.

8 Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fi ọkàn yín balẹ̀: nítorí ìpadàwá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀.

9 Ẹ má ṣe kùn sí ọmọnìkejì yín, ará, kí a má baà dá a yín lẹ́bi: kíyè síi, onídàájọ́ dúró ní ẹnu ìlẹ̀kùn.

10 Ará mi, ẹ fi àwọn wòlíì tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa ṣe àpẹẹrẹ ìyà jíjẹ, àti sùúrù.

11 Sáà wò ó, àwa a máa ka àwọn tí ó fara dà ìyà sí ẹni ìbùkún. Ẹ̀yin ti gbọ́ ti sùúrù Jóòbù, ẹ̀yin sì rí ìgbẹ̀yìn tí Olúwa ṣe; pé Olúwa kún fún ìyọ́nú, ó sì ní àánú.

12 Ṣùgbọ́n ju ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ má ṣe búra, ìbáà ṣe ìfi ọ̀run búra, tàbí ilẹ̀, tàbí ìbúra-kíbùúra mìíràn. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí “Bẹ́ẹ̀ ni” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni; àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ẹ má baà bọ́ sínú ẹ̀bi.

Àdúrà Ìgbàgbọ́

13 Inú ẹnikẹ́ni ha bàjẹ́ nínú yín bí? Jẹ́ kí ó gbàdúrà. Inú ẹnikẹ́ni ha dùn? Jẹ́ kí ó kọrin mímọ́.

14 Ẹnikẹ́ni ṣe àìsàn nínú yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ìjọ, kí wọ́n sì gbàdúrà sórí rẹ̀, kí wọn fi òróró kùn ún ní orúkọ Olúwa:

15 Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì gba aláìsàń náà là, Olúwa yóò sì gbé e dìde; bí ó bá sì ṣe pé ó ti dẹ́sẹ̀, a ó dárí jì í.

16 Ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín, kí a lè mú yín láradá. Iṣẹ́ tí àdúrà olódodo ń se ní agbára púpọ̀.

17 Ènìyàn onírúurú ìwà bí àwa ni Èlíjà, ó gbàdúrà gidigidi pé kí òjò kí ó má ṣe rọ̀, òjò kò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ fún ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà.

18 Ó sì tún gbàdúrà, ọ̀run sì tún rọ̀jò, ilẹ̀ sì so èso rẹ̀ jáde.

19 Ará, bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá sìnà kúrò nińu òtítọ́, tí ẹni kan sì yí i padà;

20 Jẹ́ kí ó mọ̀ pé, ẹni tí ó bá yí ẹlẹ́sẹ̀ kan padà kúrò nínú ìsìnà rẹ̀, yóò gba ọkàn kan là kúrò lọ́wọ́ ikú, yóò sì bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.

orí

1 2 3 4 5