6 Ẹ̀yin ti dá ẹ̀bi fún olódodo, ẹ sì ti pa á; òun kò kọ ojú ijà sí yín.
7 Nítorí náà ará, ẹ mú sùúrù títí di ìpadàwá Olúwa. Kíyèsí i, àgbẹ̀ a máa retí èso iyebíye ti ilẹ̀, a sì mú sùúrù dè é, títí di ìgbà àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò.
8 Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ mú sùúrù; ẹ fi ọkàn yín balẹ̀: nítorí ìpadàwá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀.
9 Ẹ má ṣe kùn sí ọmọnìkejì yín, ará, kí a má baà dá a yín lẹ́bi: kíyè síi, onídàájọ́ dúró ní ẹnu ìlẹ̀kùn.
10 Ará mi, ẹ fi àwọn wòlíì tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa ṣe àpẹẹrẹ ìyà jíjẹ, àti sùúrù.
11 Sáà wò ó, àwa a máa ka àwọn tí ó fara dà ìyà sí ẹni ìbùkún. Ẹ̀yin ti gbọ́ ti sùúrù Jóòbù, ẹ̀yin sì rí ìgbẹ̀yìn tí Olúwa ṣe; pé Olúwa kún fún ìyọ́nú, ó sì ní àánú.
12 Ṣùgbọ́n ju ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ má ṣe búra, ìbáà ṣe ìfi ọ̀run búra, tàbí ilẹ̀, tàbí ìbúra-kíbùúra mìíràn. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí “Bẹ́ẹ̀ ni” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni; àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ẹ má baà bọ́ sínú ẹ̀bi.