9 Ẹ má ṣe kùn sí ọmọnìkejì yín, ará, kí a má baà dá a yín lẹ́bi: kíyè síi, onídàájọ́ dúró ní ẹnu ìlẹ̀kùn.
10 Ará mi, ẹ fi àwọn wòlíì tí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní orúkọ Olúwa ṣe àpẹẹrẹ ìyà jíjẹ, àti sùúrù.
11 Sáà wò ó, àwa a máa ka àwọn tí ó fara dà ìyà sí ẹni ìbùkún. Ẹ̀yin ti gbọ́ ti sùúrù Jóòbù, ẹ̀yin sì rí ìgbẹ̀yìn tí Olúwa ṣe; pé Olúwa kún fún ìyọ́nú, ó sì ní àánú.
12 Ṣùgbọ́n ju ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ má ṣe búra, ìbáà ṣe ìfi ọ̀run búra, tàbí ilẹ̀, tàbí ìbúra-kíbùúra mìíràn. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí “Bẹ́ẹ̀ ni” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni; àti “Bẹ́ẹ̀ kọ́” yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ẹ má baà bọ́ sínú ẹ̀bi.
13 Inú ẹnikẹ́ni ha bàjẹ́ nínú yín bí? Jẹ́ kí ó gbàdúrà. Inú ẹnikẹ́ni ha dùn? Jẹ́ kí ó kọrin mímọ́.
14 Ẹnikẹ́ni ṣe àìsàn nínú yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ìjọ, kí wọ́n sì gbàdúrà sórí rẹ̀, kí wọn fi òróró kùn ún ní orúkọ Olúwa:
15 Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì gba aláìsàń náà là, Olúwa yóò sì gbé e dìde; bí ó bá sì ṣe pé ó ti dẹ́sẹ̀, a ó dárí jì í.