11 Manoa bá gbéra, ó bá tẹ̀lé iyawo rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ ọkunrin náà, ó bi í pé, “Ṣé ìwọ ni o bá obinrin yìí sọ̀rọ̀?”Ọkunrin náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”
12 Manoa tún bèèrè pé, “Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ, báwo ni ìgbé ayé ọmọ náà yóo rí? Irú kí ni yóo sì máa ṣe?”
13 Angẹli OLUWA náà dá Manoa lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí mo sọ fún obinrin yìí ni kí o kíyèsí.
14 Kò gbọdọ̀ fẹnu kan ohunkohun tí ó bá jáde láti inú èso àjàrà, kò gbọdọ̀ mu waini tabi ọtí líle tabi kí ó jẹ ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún un ni kí ó ṣe.”
15 Manoa dá angẹli OLUWA náà lóhùn, ó ní, “Jọ̀wọ́, dúró díẹ̀ kí á se ọmọ ewúrẹ́ kan fún ọ.”
16 Angẹli OLUWA náà dá Manoa lóhùn, ó ní, “Bí o bá dá mi dúró, n kò ní jẹ ninu oúnjẹ rẹ, ṣugbọn tí o bá fẹ́ tọ́jú ohun tí o fẹ́ fi rú ẹbọ sísun, OLUWA ni kí o rú u sí.” Manoa kò mọ̀ pé angẹli OLUWA ni.
17 Manoa bá bèèrè lọ́wọ́ angẹli OLUWA náà, ó ní, “Kí ni orúkọ rẹ kí á lè dá ọ lọ́lá nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ.”