10 Baba rẹ̀ bá lọ sí ọ̀dọ̀ obinrin náà. Samsoni se àsè ńlá kan níbẹ̀, nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọdọmọkunrin máa ń ṣe nígbà náà.
11 Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i, wọ́n mú ọgbọ̀n ninu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ wá láti wà pẹlu rẹ̀.
12 Samsoni bá sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n pa àlọ́ kan fun yín, bí ẹ bá lè túmọ̀ àlọ́ náà láàrin ọjọ́ meje tí a ó fi se àsè igbeyawo yìí, n óo fun yín ní ọgbọ̀n ẹ̀wù funfun ati ọgbọ̀n aṣọ àríyá.
13 Ṣugbọn bí ẹ kò bá lè túmọ̀ àlọ́ náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóo fún mi ní ẹ̀wù funfun kọ̀ọ̀kan ati aṣọ àríyá kọ̀ọ̀kan.”Wọ́n bá dáhùn pé, “Pa àlọ́ rẹ kí á gbọ́.”
14 Ó bá pa àlọ́ náà fún wọn, ó ní,“Láti inú ọ̀jẹun ni nǹkan jíjẹ tií wá,láti inú alágbára sì ni nǹkan dídùn tií wá.”Wọn kò sì lè túmọ̀ àlọ́ rẹ̀ fún ọjọ́ mẹta.
15 Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹrin, wọ́n wá bẹ iyawo Samsoni pé, “Tan ọkọ rẹ kí ó sọ ìtumọ̀ àlọ́ náà fún wa, láì ṣe bẹ́ẹ̀, a óo sun ìwọ ati ilé baba rẹ níná. Àbí pípè tí o pè wá wá sí ibí yìí, o fẹ́ sọ wá di aláìní ni?”
16 Iyawo Samsoni bá bẹ̀rẹ̀ sì sọkún níwájú rẹ̀, ó ní, “O kò fẹ́ràn mi rárá, irọ́ ni ò ń pa fún mi. O kórìíra mi; nítorí pé o pa àlọ́ fún àwọn ará ìlú mi, o kò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.”Samsoni bá dá a lóhùn pé, “Ohun tí n kò sọ fún baba tabi ìyá mi, n óo ti ṣe wá sọ fún ọ?”