1 Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ní àkókò ìkórè ọkà, Samsoni mú ọmọ ewúrẹ́ kan, ó lọ bẹ iyawo rẹ̀ wò. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó ní, “Mo fẹ́ wọlé lọ bá iyawo mi ninu yàrá.”Ṣugbọn baba iyawo rẹ̀ kò jẹ́ kí ó wọlé lọ bá a.
2 Baba iyawo rẹ̀ wí fún un pé, “Mo rò pé lóòótọ́ ni o kórìíra iyawo rẹ, nítorí náà, mo ti fi fún ẹni tí ó jẹ́ ọrẹ rẹ tímọ́tímọ́, ninu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ. Ṣé ìwọ náà rí i pé àbúrò rẹ̀ lẹ́wà jù ú lọ, jọ̀wọ́ fẹ́ ẹ dípò rẹ̀.”
3 Samsoni dáhùn pé, “Bí mo bá ṣe àwọn ará Filistia ní ibi ní àkókò yìí, n kò ní jẹ̀bi wọn.”
4 Samsoni bá lọ, ó mú ọọdunrun (300) kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láàyè, ó wá ìtùfù, ó sì so àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà ní ìrù pọ̀ ní meji meji, ó fi ìtùfù sí ààrin ìrù wọn.