17 Ó fi ìṣákọ́lẹ̀ náà jíṣẹ́ fún Egiloni, ọba ilẹ̀ Moabu. Egiloni yìí jẹ́ ẹni tí ó sanra rọ̀pọ̀tọ̀.
18 Nígbà tí Ehudu fi ìṣákọ́lẹ̀ náà jíṣẹ́ tán, ó ní kí àwọn tí wọ́n rù ú máa pada lọ.
19 Òun nìkan bá pada ní ibi òkúta tí wọ́n gbẹ́, tí ó wà lẹ́bàá Giligali, ó tọ ọba lọ, ó ní, “Kabiyesi, mo ní iṣẹ́ àṣírí kan tí mo fẹ́ jẹ́ fún ọ.”Ọba bá sọ fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n jáde, gbogbo wọn sì jáde.
20 Ehudu bá tọ̀ ọ́ lọ, níbi tí òun nìkan jókòó sí ninu yàrá tútù kan, lórí òrùlé ilé rẹ̀, ó wí fún un pé, “Ọlọ́run rán mi ní iṣẹ́ kan sí ọ,” ọba bá dìde níbi tí ó jókòó sí.
21 Ehudu bá fi ọwọ́ òsì fa idà tí ó so mọ́ itan rẹ̀ ọ̀tún yọ, ó sì tì í bọ ọba Egiloni níkùn.
22 Idà yìí wọlé tèèkùtèèkù, ọ̀rá sì padé mọ́ ọn, nítorí pé kò fa idà náà yọ kúrò ní ikùn ọba, ìfun ọba sì tú jáde.
23 Ehudu bá jáde, ó sì fi kọ́kọ́rọ́ ti gbogbo ìlẹ̀kùn yàrá orí òrùlé náà.