11 Ẹ tẹ́tí sí ohùn àwọn akọrin lẹ́bàá odò,ibẹ̀ ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ́gun OLUWA,ọ̀rọ̀ ìṣẹ́gun àwọn eniyan rẹ̀ ní Israẹli.Àwọn eniyan OLUWA sì yan jáde láti ẹnubodè ìlú wọn.
12 Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀! Debora!Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀, kí o dárin!Dìde, Baraki, máa kó àwọn tí o kó lógun lọ,ìwọ ọmọ Abinoamu!
13 Àwọn akikanju yòókù bẹ̀rẹ̀ sí yan bọ̀,àwọn eniyan OLUWA náà sì ń wọ́ bọ̀,láti gbógun ti alágbára.
14 Wọ́n gbéra láti Efuraimu lọ sí àfonífojì náà,wọ́n tẹ̀lé ọ, ìwọ Bẹnjamini pẹlu àwọn eniyan rẹ.Àwọn ọ̀gágun wá láti Makiri,àwọn olórí ogun sì wá láti Sebuluni.
15 Àwọn ìjòyè Isakari náà bá Debora wá,àwọn ọmọ Isakari jẹ́ olóòótọ́ sí Baraki,wọ́n sì dà tẹ̀lé e lẹ́yìn lọ sí àfonífojì.Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ṣiyèméjì,ìmọ̀ wọn kò ṣọ̀kan láti wá.
16 Kí ló dé tí o fi dúró lẹ́yìn láàrin àwọn agbo aguntan?Tí o fi ń gbọ́ bí àwọn olùṣọ́-aguntan ti ń fọn fèrè fún àwọn aguntan wọn.Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ṣiyèméjì,ìmọ̀ wọn kò ṣọ̀kan láti wá.
17 Àwọn ará Gileadi dúró ní ìlà oòrùn odò Jọdani,kí ló dé tí ẹ̀yà Dani fi dúró ní ìdí ọkọ̀ ojú omi?Àwọn ẹ̀yà Aṣeri jókòó létí òkun,wọ́n wà ní ẹsẹ̀ odò.