Daniẹli 10 BM

Ìran tí Daniẹli Rí ní Odò Tigirisi

1 Ní ọdún kẹta tí Kirusi jọba ní Pasia, Daniẹli, (tí à ń pè ní Beteṣasari) rí ìran kan. Òtítọ́ ni ìran náà, ó ṣòro láti túmọ̀, ṣugbọn a la ìran náà ati ìtumọ̀ rẹ̀ yé Daniẹli.

2 Ní àkókò náà, èmi Daniẹli ń ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹta.

3 N kò jẹ oúnjẹ aládùn, n kò jẹran, n kò mu ọtí, n kò sì fi òróró para ní odidi ọ̀sẹ̀ mẹtẹẹta náà.

4 Ní ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù kinni ọdún tí à ń wí yìí, mo dúró létí odò Tigirisi.

5 Bí mo ti gbójú sókè, mo rí ọkunrin kan tí ó wọ aṣọ funfun, ó fi àmùrè wúrà ṣe ìgbànú.

6 Ara rẹ̀ ń dán bí òkúta olówó iyebíye tí à ń pè ní bẹrili. Ojú rẹ̀ ń kọ mànà bíi mànàmáná, ẹyinjú rẹ̀ sì ń tàn bí iná. Ọwọ́ ati ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí idẹ dídán, ohùn rẹ̀ sì dàbí ohùn ọpọlọpọ eniyan.

7 Èmi nìkan ni mo rí ìran yìí, àwọn tí wọ́n wà pẹlu mi kò rí i, ṣugbọn ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì sápamọ́.

8 Èmi nìkan ni mo kù tí mo sì rí ìran ńlá yìí. Kò sí agbára kankan fún mi mọ́; ojú mi sì yipada, ó wá rẹ̀ mí dẹẹ.

9 Mo bá gbọ́ tí ó sọ̀rọ̀, nígbà tí mo gbọ́ ohùn rẹ̀, mo dojúbolẹ̀, oorun sì gbé mi lọ.

10 Ọwọ́ kan bá dì mí mú, ó gbé mi nílẹ̀, mo da ọwọ́ ati orúnkún mi délẹ̀. Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n fún ìbẹ̀rù.

11 Ẹni náà pè mí, ó ní, “Daniẹli, ẹni tí Ọlọrun fẹ́ràn! Dìde nàró kí o gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ, nítorí ìwọ ni a rán mi sí.” Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, mo dìde nàró, ṣugbọn mo ṣì tún ń gbọ̀n.

12 Ó bá dá mi lọ́kàn le, ó ní, “Má bẹ̀rù, Daniẹli, nítorí láti ọjọ́ tí o ti pinnu láti mòye, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọrun rẹ, gbogbo ohun tí ò ń bèèrè ni a ti gbọ́, adura rẹ ni mo sì wá dáhùn.

13 Angẹli, aláṣẹ ìjọba Pasia dè mí lọ́nà fún ọjọ́ mọkanlelogun; ṣugbọn Mikaeli, ọ̀kan ninu àwọn olórí aláṣẹ, ni ó wá ràn mí lọ́wọ́; nítorí wọ́n dá mi dúró sọ́dọ̀ aláṣẹ ìjọba Pasia.

14 Kí o lè mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí àwọn eniyan rẹ lẹ́yìn ọ̀la ni mo ṣe wá, nítorí ìran ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú ni ìran tí o rí.”

15 Nígbà tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tán, mo dojúbolẹ̀, mo sì ya odi.

16 Ẹnìkan tí ó dàbí eniyan wá, ó fi ọwọ́ kàn mí ní ètè; ẹnu mi bá yà, mo sì sọ̀rọ̀. Mo sọ fún ẹni tí ó dúró tì mí pé, “Olúwa mi, gbogbo ara ni ó wó mi, nítorí ìran tí mo rí, ó sì ti rẹ̀ mí patapata.

17 N kò ní agbára kankan mọ́, kò sì sí èémí kankan ninu mi, báwo ni èmi iranṣẹ rẹ ti ṣe lè bá ìwọ oluwa mi sọ̀rọ̀?”

18 Ẹni tí ó dàbí eniyan bá tún fi ọwọ́ kàn mí, ó sì fún mi ní okun.

19 Ó ní, “Ìwọ tí Ọlọrun fẹ́ràn, má bẹ̀rù, alaafia ni, dá ara yá, kí o sì ṣe ọkàn gírí.”Nígbà tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tán, mo tún lágbára sí i; mo bá dáhùn pé, “olúwa mi, máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ lọ, nítorí ìwọ ni ó fún mi lágbára sí i.”

20 Ó bi mí pé, “Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí mo fi tọ̀ ọ́ wá? Nisinsinyii n óo pada lọ bá aláṣẹ ìjọba Pasia jà, tí mo bá bá a jà tán, aláṣẹ ìjọba Giriki yóo wá.

21 Kò sí ẹni tí yóo gbèjà mi ninu nǹkan wọnyi àfi Mikaeli, olùṣọ́ Israẹli; Ṣugbọn n óo sọ ohun tí ó wà ninu Ìwé Òtítọ́ fún ọ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12