Daniẹli 2 BM

Àlá Nebukadinesari

1 Ní ọdún keji tí Nebukadinesari gun orí oyè, ó lá àwọn àlá kan; àlá náà bà á lẹ́rù tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi lè sùn mọ́ lóru ọjọ́ náà.

2 Nítorí náà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n pe àwọn pidánpidán, ati àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn oṣó ati àwọn ará Kalidea jọ, kí wọ́n wá rọ́ àlá òun fún òun. Gbogbo wọn sì wá siwaju ọba.

3 Ọba sọ fún wọn pé, “Mo lá àlá kan tí ó bà mí lẹ́rù pupọ, mo sì fẹ́ mọ ìtumọ̀ rẹ̀.”

4 Àwọn ará Kalidea bá dá ọba lóhùn pé, “Kí ọba pẹ́! Rọ́ àlá rẹ fún àwa iranṣẹ rẹ, a óo sì túmọ̀ rẹ̀.”

5 Ṣugbọn ọba dá wọn lóhùn, pé, “Ohun tí mo bá sọ abẹ ni ó gé e; bí ẹ kò bá lè rọ́ àlá náà fún mi, kí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fà yín ya ní tapá-titan, ilé yín yóo sì di àlàpà.

6 Ṣugbọn bí ẹ bá rọ́ àlá náà, tí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, ẹ óo gba ẹ̀bùn, ìdálọ́lá ati ẹ̀yẹ ńlá, nítorí náà ẹ rọ́ àlá náà fún mi, kí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”

7 Wọ́n dá ọba lóhùn lẹẹkeji pé, “Kí kabiyesi rọ́ àlá rẹ̀ fún wa, a óo sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”

8 Ọba dá wọn lóhùn pé, “Mo mọ̀ dájú pé ẹ kàn fẹ́ máa fi ọgbọ́n fi àkókò ṣòfò ni, nítorí ẹ ti mọ̀ pé bí mo ti wí ni n óo ṣe.

9 Bí ẹ kò bá rọ́ àlá mi fún mi, ìyà kanṣoṣo ni n óo fi jẹ yín. Gbogbo yín ti gbìmọ̀ pọ̀ láti máa parọ́, ati láti máa fi ọgbọ́n fi àkókò ṣòfò. Ẹ rọ́ àlá mi fún mi, n óo sì mọ̀ dájú pé ẹ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”

10 Wọ́n dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ẹni náà láyé yìí, tí ó lè sọ ohun tí kabiyesi fẹ́ kí á sọ, kò sí ọba ńlá tabi alágbára kankan tí ó tíì bèèrè irú nǹkan yìí lọ́wọ́ pidánpidán kan, tabi lọ́wọ́ àwọn aláfọ̀ṣẹ, tabi lọ́wọ́ àwọn ará Kalidea rí.

11 Ohun tí ọba ń bèèrè yìí le pupọ, kò sí ẹni tí ó lè ṣe é, àfi àwọn oriṣa, nítorí pé àwọn kì í ṣe ẹlẹ́ran ara.”

12 Nítorí náà inú ọba ru, ó sì bínú gidigidi, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run.

13 Àṣẹ jáde lọ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n; wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wá Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti pa wọ́n.

Ọlọrun fi Àlá Ọba ati Ìtumọ̀ Rẹ̀ Han Daniẹli

14 Daniẹli bá lọ sí ọ̀dọ̀ Arioku, tí ọba pàṣẹ fún pé kí ó pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni; ó fi ọgbọ́n ati ìrẹ̀lẹ̀ bá a sọ̀rọ̀,

15 ó ní, “Kí ló dé tí àṣẹ ọba fi le tó báyìí?” Arioku bá sọ bí ọ̀rọ̀ ti rí fún un.

16 Lẹsẹkẹsẹ, Daniẹli lọ bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ọba pé kí ó dá àkókò fún òun, kí òun lè wá rọ́ àlá náà fún ọba, kí òun sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.

17 Daniẹli bá lọ sí ilé, ó sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀: Hananaya, Miṣaeli, ati Asaraya,

18 pé kí wọ́n gbadura sí Ọlọrun ọ̀run fún àánú láti mọ àlá ọba ati ìtumọ̀ rẹ̀, kí wọ́n má baà pa òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ òun run pẹlu àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni.

19 Ọlọrun bá fi àṣírí náà han Daniẹli ní ojúran, lóru. Ó sì yin Ọlọrun ọ̀run lógo.

20 Ó ní, “Ẹni ìyìn ni Ọlọrun títí ayérayé,ẹni tí ó ní ọgbọ́n ati agbára.

21 Òun ní ń yí ìgbà ati àkókò pada;òun níí mú ọba kan kúrò lórí ìtẹ́,tíí sì í fi òmíràn jẹ.Òun níí fi ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́ntíí sì í fi ìmọ̀ fún àwọn ọ̀mọ̀ràn.

22 Òun níí fi àṣírí ati ohun ìjìnlẹ̀ hàn;ó mọ ohun tí ó wà ninu òkùnkùn,ìmọ́lẹ̀ sì ń bá a gbé.

23 Ìwọ Ọlọrun àwọn baba mi,ni mo fi ọpẹ́ ati ìyìn fún,nítorí o fún mi ní ọgbọ́n ati agbára,o sì ti fi ohun tí a bèèrè hàn mí,nítorí o ti fi ohun tí ọba ń bèèrè hàn wá.”

Daniẹli Rọ́ Àlá Ọba, Ó sì Sọ Ìtumọ̀ Rẹ̀

24 Daniẹli bá lọ sí ọ̀dọ̀ Arioku, ẹni tí ọba yàn pé kí ó pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run, ó sọ fún un pé, “Má pa àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run, mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, n óo sì túmọ̀ àlá rẹ̀ fún un.”

25 Arioku bá mú Daniẹli lọ sí ọ̀dọ̀ ọba kíákíá. Ó sọ fún ọba pé: “Kabiyesi, mo ti rí ọkunrin kan ninu àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú wá láti Juda, tí ó le túmọ̀ àlá náà fún ọba.”

26 Ọba bi Daniẹli, tí wọ́n sọ ní Beteṣasari ní èdè Babiloni pé, “Ǹjẹ́ o lè rọ́ àlá mi fún mi, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀?”

27 Daniẹli dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ọlọ́gbọ́n kan, tabi aláfọ̀ṣẹ, tabi pidánpidán, tabi awòràwọ̀ tí ó lè sọ àṣírí ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ọba ń bèèrè yìí fún un.

28 Ṣugbọn Ọlọrun kan ń bẹ ní ọ̀run, tí ń fi àṣírí nǹkan ìjìnlẹ̀ hàn. Òun ni ó fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la han Nebukadinesari ọba. Àlá tí o lá, ati ìran tí o rí ní orí ibùsùn rẹ nìyí:

29 “Kabiyesi! Bí o ti sùn, ò ń ronú ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la, ẹni tí ń fi ohun ìjìnlẹ̀ han ni sì fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ hàn ọ́.

30 Ní tèmi, kì í ṣe pé mo gbọ́n ju àwọn yòókù lọ ni a ṣe fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí hàn mí, bíkòṣe pé kí ọba lè mọ ìtumọ̀ rẹ̀, kí òye ohun tí ó ń rò sì lè yé e.

31 “Kabiyesi, o rí ère kan níwájú rẹ ní ojúran, ère yìí tóbi gan-an, ó mọ́lẹ̀, ó ń dán, ìrísí rẹ̀ sì bani lẹ́rù.

32 Wúrà ni orí rẹ̀, àyà ati apá rẹ̀ jẹ́ fadaka, ikùn rẹ̀ títí dé itan sì jẹ́ idẹ.

33 Irin ni òkè ẹsẹ̀ rẹ̀, ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ irin tí a lú pọ̀ mọ́ amọ̀.

34 Bí o ti ń wò ó, òkúta kan là, ó sì ré bọ́ láti òkè, ó bá ère náà ní ẹsẹ̀ mejeeji tí ó jẹ́ àdàlú irin ati amọ̀, mejeeji sì fọ́ túútúú.

35 Lẹ́sẹ̀kan náà òkúta yìí bá fọ́ gbogbo ère náà, ati irin, ati amọ̀, ati idẹ, ati fadaka ati wúrà, ó rún gbogbo wọn wómúwómú, títí wọ́n fi dàbí ìyàngbò ní ibi ìpakà. Lẹ́yìn náà, afẹ́fẹ́ fẹ́ wọn lọ, a kò sì rí wọn mọ́ rárá. Òkúta tí ó kọlu ère náà di òkè ńlá, ó sì bo gbogbo ayé.

36 “Àlá náà nìyí; nisinsinyii, n óo sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba.

37 Kabiyesi, ìwọ ọba àwọn ọba ni Ọlọrun ọ̀run fún ní ìjọba, agbára, ipá ati ògo.

38 Ọlọrun fi gbogbo eniyan jìn ọ́, níbi yòówù tí wọn ń gbé, ati gbogbo ẹranko, ati gbogbo ẹyẹ, pé kí o máa jọba lórí wọn, ìwọ ni orí wúrà náà.

39 Lẹ́yìn rẹ ni ìjọba mìíràn yóo dìde tí kò ní lágbára tó tìrẹ. Lẹ́yìn èyí ni ìjọba kẹta, tí ó jẹ́ ti idẹ, yóo jọba lórí gbogbo ayé.

40 Nígbà tí ó bá yá, ìjọba kẹrin yóo dé, tí yóo le koko bíi irin (nítorí pé irin a máa fọ́ nǹkan sí wẹ́wẹ́ ni); bíi irin ni ìjọba yìí yóo fọ́ àwọn tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀ túútúú.

41 Bí o sì ti rí ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ ati ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ tí ó jẹ́ àdàlú irin ati amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yìí yóo pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Ṣugbọn agbára irin yóo hàn lára rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí o ti rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀.

42 Bí ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ sì ti jẹ́ àdàlú amọ̀ ati irin, bẹ́ẹ̀ ni apá kan ìjọba náà yóo lágbára, apá kan kò sì ní lágbára.

43 Bí o ti rí amọ̀ tí ó dàpọ̀ mọ́ irin, bẹ́ẹ̀ ni àwọn apá kinni keji yóo máa dàpọ̀ ní igbeyawo, ṣugbọn wọn kò ní darapọ̀, gẹ́gẹ́ bí irin kò ti lè darapọ̀ mọ́ amọ̀.

44 Ní àkókò àwọn ìjọba wọnyi ni Ọlọrun ọ̀run yóo gbé ìjọba kan dìde tí a kò ní lè parun, a kò sì ní fi ìjọba náà fún ẹlòmíràn. Yóo fọ́ àwọn ìjọba wọnyi túútúú, yóo pa wọ́n run, yóo sì dúró laelae.

45 Bí o ti rí i pé ara òkè kan ni òkúta yìí ti là, láìjẹ́ pé eniyan kan ni ó là á, tí o sì rí i pé ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fadaka ati wúrà túútúú, Ọlọrun tí ó tóbi ni ó fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la han ọba. Òtítọ́ ni àlá yìí, ìtumọ̀ rẹ̀ sì dájú.”

Ọba fún Daniẹli ní Ẹ̀bùn

46 Ọba bá wólẹ̀ níwájú Daniẹli, ó fi orí balẹ̀ fún un, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n rúbọ kí wọ́n sì sun turari sí Daniẹli.

47 Ọba sọ fún Daniẹli pé, “Láìsí àní àní, Ọlọrun rẹ ni Ọlọrun àwọn ọlọrun, ati OLUWA àwọn ọba, òun níí fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ han eniyan, nítorí pé àṣírí ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí gan-an ni o sọ.”

48 Ọba dá Daniẹli lọ́lá, ó kó oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn ńláńlá fún un, ó sì fi ṣe olórí gbogbo agbègbè Babiloni, ati olórí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ní Babiloni.

49 Daniẹli gba àṣẹ lọ́wọ́ ọba, ó fi Ṣadiraki, Meṣaki, ati Abedinego ṣe alákòóso àwọn agbègbè Babiloni, ṣugbọn òun wà ní ààfin.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12