Daniẹli 11 BM

1 “Ní ọdún kinni ìjọba Dariusi ará Mede, mo dúró tì í láti mú un lọ́kàn le ati láti bá a fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.

2 Nisinsinyii, n óo fi òtítọ́ hàn ọ́.”Angẹli náà tún ní, “Àwọn ọba mẹta ni yóo jẹ sí i ní Pasia; ẹkẹrin yóo ní ọrọ̀ pupọ ju gbogbo àwọn yòókù lọ; nígbà tí ó bá sì ti ipa ọrọ̀ rẹ̀ di alágbára tán, yóo ti gbogbo eniyan nídìí láti bá ìjọba Giriki jagun.

Ìjọba Ijipti ati ti Siria

3 “Ọba olókìkí kan yóo wá gorí oyè, pẹlu ipá ni yóo máa fi ṣe ìjọba tirẹ̀, yóo sì máa ṣe bí ó bá ti wù ú.

4 Lẹ́yìn tí ó bá jọba, ìjọba rẹ̀ yóo pín sí ọ̀nà mẹrin. Àwọn ọba tí yóo jẹ lẹ́yìn rẹ̀ kò ní jẹ́ láti inú ìran rẹ̀, kò sì ní sí èyí tí yóo ní agbára tó o ninu wọn; nítorí a óo gba ìjọba rẹ̀, a óo sì fún àwọn ẹlòmíràn.

5 “Ọba Ijipti ní ìhà gúsù yóo lágbára, ṣugbọn ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè rẹ̀ yóo lágbára jù ú lọ, ìjọba rẹ̀ yóo sì tóbi ju ti ọba lọ.

6 Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ọba Ijipti yóo ní àjọṣepọ̀ pẹlu ọba Siria, ní ìhà àríwá, ọmọbinrin ọba Ijipti yóo wá sí ọ̀dọ̀ ọba Siria láti bá a dá majẹmu alaafia; ṣugbọn agbára ọmọbinrin náà yóo dínkù, ọba pàápàá ati ọmọ rẹ̀ kò sì ní tọ́jọ́. A óo kọ obinrin náà sílẹ̀, òun ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀, ati alátìlẹ́yìn rẹ̀.

7 Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ yóo jọba ní ipò rẹ̀, yóo wá pẹlu ogun, yóo wọ ìlú olódi ọba Siria, yóo bá wọn jagun, yóo sì ṣẹgun wọn.

8 Yóo kó àwọn oriṣa wọn, ati àwọn ère wọn lọ sí ilẹ̀ Ijipti, pẹlu àwọn ohun èlò olówó iyebíye wọn tí wọ́n fi wúrà ati fadaka ṣe; kò sì ní bá ọba Siria jagun mọ́ fún ọdún bíi mélòó kan.

9 Ọba Siria yóo wá gbógun ti ọba Ijipti, ṣugbọn yóo sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀.

10 “Àwọn ọmọ ọba Siria yóo gbá ogun ńlá jọ, wọn yóo sì kó ogun wọn wá, wọn yóo jà títí wọn yóo fi wọ ìlú olódi ti ọ̀tá wọn.

11 Inú yóo bí ọba Ijipti, yóo sì lọ bá ọba Siria jagun. Ọba Siria yóo kó ọpọlọpọ ogun jọ, ṣugbọn Ijipti yóo ṣẹgun rẹ̀.

12 Ọba Ijipti óo máa gbéraga nítorí ìṣẹ́gun rẹ̀ lórí ọpọlọpọ ogun yìí, yóo sì pa ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun, ṣugbọn kò ní borí.

13 “Nítorí pé ọba Siria yóo tún pada lọ, yóo kó ogun jọ, tí yóo pọ̀ ju ti iṣaaju lọ. Nígbà tí ó bá yá, lẹ́yìn ọpọlọpọ ọdún, yóo pada wá pẹlu ikọ̀ ọmọ ogun tí ó lágbára, pẹlu ọpọlọpọ ihamọra ati ohun ìjà.

14 Ní àkókò náà, ọ̀pọ̀ eniyan yóo dìde sí ọba Ijipti; àwọn oníjàgídíjàgan láàrin àwọn eniyan rẹ̀ yóo dìde kí ìran yìí lè ṣẹ; ṣugbọn wọn kò ní borí.

15 Ọba Siria yóo wá dóti ìlú olódi kan, yóo sì gbà á. Àwọn ọmọ ogun Ijipti kò ní lágbára láti dojú ìjà kọ ọ́, àwọn akikanju wọn pàápàá kò ní lágbára mọ́ láti jagun.

16 Ọba Siria yóo ṣe wọ́n bí ó ti fẹ́ láìsí àtakò, yóo dúró ní Ilẹ̀ Dáradára náà, gbogbo rẹ̀ yóo sì wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.

17 “Ọba Siria yóo múra láti wá pẹlu gbogbo agbára ìjọba rẹ̀, yóo bá ọba Ijipti dá majẹmu alaafia, yóo sì mú majẹmu náà ṣẹ. Yóo fi ọmọbinrin rẹ̀ fún ọba Ijipti ní aya, kí ó lè ṣẹgun ọba Ijipti. Ṣugbọn yóo kùnà ninu ète rẹ̀.

18 Lẹ́yìn náà, yóo bá àwọn orílẹ̀-èdè ati àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní etíkun jà, yóo sì ṣẹgun ọpọlọpọ wọn. Ṣugbọn olórí-ogun kan yóo ṣẹgun rẹ̀, yóo sì pa òun náà run.

19 Yóo pada sí ìlú olódi ti ara rẹ̀, ṣugbọn ijamba yóo ṣe é, yóo sì ṣubú lójú ogun; yóo sì fi bẹ́ẹ̀ parẹ́ patapata.

20 “Ọba mìíràn yóo jẹ lẹ́yìn rẹ̀, yóo sì rán agbowóopá kan kí ó máa gba owó-odè kiri ní gbogbo ìjọba rẹ̀; ní kò pẹ́ kò jìnnà, a óo pa ọba náà, ṣugbọn kò ní jẹ́ ní gbangba tabi lójú ogun.”

Ọba Burúkú tí Ó Jẹ ní Siria

21 Angẹli náà tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé, “Ọba tí yóo tún jẹ ní Siria yóo jẹ́ ọba burúkú. Kì í ṣe òun ni oyè yóo tọ́ sí, ṣugbọn yóo dé lójijì, yóo sì fi àrékérekè gba ìjọba.

22 Yóo tú àwọn ọmọ ogun ká níwájú rẹ̀, ati ọmọ aládé tí wọn bá dá majẹmu.

23 Yóo máa fi ẹ̀tàn bá àwọn orílẹ̀-èdè dá majẹmu. Yóo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbilẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè tí ó jọba lé lórí kéré.

24 Lójijì yóo wá sí àwọn ibi tí ó ní ọrọ̀ jùlọ ní agbègbè náà, yóo máa ṣe ohun tí àwọn baba ńlá rẹ̀ kò ṣe rí. Yóo máa pín ìkógun rẹ̀ fún wọn. Yóo máa wá ọ̀nà ti yóo fi gba àwọn ìlú olódi; ṣugbọn fún ìgbà díẹ̀ ni.

25 “Yóo fi gbogbo agbára ati ìgboyà rẹ̀ gbé ogun ńlá ti ọba Ijipti; ọba Ijipti náà yóo gbé ogun ńlá tì í, ṣugbọn kò ní lè dúró níwájú ọba Ijipti nítorí pé wọn yóo dìtẹ̀ mọ́ ọn.

26 Àwọn tí wọ́n ń bá a jẹ oúnjẹ àdídùn pọ̀ gan-an ni yóo dìtẹ̀ mọ́ ọn; gbogbo ogun rẹ̀ ni yóo túká, ọpọlọpọ yóo sì kú.

27 Àwọn ọba mejeeji ni yóo pinnu láti hùwà àrékérekè, wọn ó sì máa purọ́ tan ara wọn jẹ níbi tí wọ́n ti jọ ń jẹun; ṣugbọn òfo ni ọgbọ́n àrékérekè wọn yóo já sí; nítorí pé òpin wọn yóo dé ní àkókò tí a ti pinnu.

28 Ọba Siria yóo wá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹlu gbogbo ìkógun rẹ̀. Ṣugbọn yóo pinnu ní ọkàn rẹ̀ láti gbógun ti majẹmu mímọ́ Ọlọrun ati Israẹli. Nígbà tí ó bá ṣe bí ó ti fẹ́ tán, yóo pada sí ilẹ̀ rẹ̀.

29 “Ní àkókò tí a ti pinnu, yóo tún gbógun ti ilẹ̀ Ijipti, ṣugbọn nǹkan kò ní rí bíi ti àkọ́kọ́ fún un;

30 nítorí pé, àwọn ọmọ ogun Kitimu tí wọ́n wà ninu ọkọ̀ ojú omi yóo gbógun tì í.“Ẹ̀rù yóo bà á, yóo sì sá pada, yóo fi ibinu ńlá gbógun ti majẹmu mímọ́ Ọlọrun ati Israẹli, yóo sì máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn tí wọ́n ti kọ majẹmu náà sílẹ̀.

31 Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóo wá, wọn yóo sọ Tẹmpili ati ibi ààbò di aláìmọ́, wọn yóo dáwọ́ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo dúró, wọn yóo sì gbé ohun ìríra tíí fa ìsọdahoro kalẹ̀.

32 Pẹlu ẹ̀tàn, ọba yìí yóo mú àwọn tí wọ́n kọ majẹmu náà sílẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́; ṣugbọn àwọn tí wọ́n mọ Ọlọrun yóo dúró ṣinṣin, wọn óo sì ṣe ẹ̀tọ́.

33 Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́gbọ́n láàrin wọn óo máa la ọpọlọpọ lọ́yẹ, ṣugbọn fún ìgbà díẹ̀, wọn óo kú ikú idà, a óo dáná sun wọ́n, a óo kó wọn lẹ́rù, a óo sì kó wọn ní ẹrú lọ.

34 Nígbà tí a bá ṣẹgun wọn, wọn yóo rí ìrànlọ́wọ́ díẹ̀ gbà, ọpọlọpọ yóo sì faramọ́ wọn pẹlu ẹ̀tàn.

35 Díẹ̀ ninu àwọn ọlọ́gbọ́n yóo kú lójú ogun, a óo fi dán àwọn ọmọ Israẹli wò láti wẹ̀ wọ́n mọ́ ati láti mú gbogbo àbààwọ́n wọn kúrò títí di àkókò ìkẹyìn, ní àkókò tí Ọlọrun ti pinnu.

36 “Ohun tí ó bá wu ọba náà ni yóo máa ṣe; yóo gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo oriṣa lọ, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo máa sọ̀rọ̀ tó lòdì sí Ọlọrun àwọn ọlọrun, yóo sì bẹ̀rẹ̀ sí lágbára sí i títí ọjọ́ ibinu tí a dá fún un yóo fi pé; nítorí pé ohun tí Ọlọrun ti pinnu yóo ṣẹ.

37 Kò ní náání oriṣa tí àwọn baba rẹ̀ ń sìn, kò sì ní bìkítà fún èyí tí àwọn obinrin fẹ́ràn; kò ní bìkítà fún oriṣa kankan, nítorí pé yóo gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo wọn lọ.

38 Dípò gbogbo wọn, yóo máa bọ oriṣa àwọn ìlú olódi; oriṣa tí àwọn baba rẹ̀ kò mọ̀ rí ni yóo máa sìn, yóo máa fún un ní wúrà ati fadaka, òkúta iyebíye ati àwọn ẹ̀bùn olówó iyebíye.

39 Pẹlu ìrànlọ́wọ́ àwọn tí ń bọ oriṣa àjèjì kan, yóo bá àwọn ìlú olódi tí wọ́n lágbára jùlọ jà. Yóo bu ọlá fún àwọn tí wọ́n bá yẹ́ ẹ sí. Yóo fi wọ́n jẹ olórí ọpọlọpọ eniyan; yóo sì fi ilẹ̀ ṣe ẹ̀bùn fún àwọn tí wọ́n bá fún un lówó.

40 “Nígbà tí àkókò ìkẹyìn bá dé, ọba ilẹ̀ Ijipti yóo gbógun tì í; ṣugbọn ọba Siria yóo gbógun tì í bí ìjì líle, pẹlu kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ati ọpọlọpọ ọkọ̀ ojú omi. Yóo kọlu àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri yóo sì bò wọ́n mọ́lẹ̀ lọ bí àgbàrá òjò.

41 Yóo wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà. Ẹgbẹẹgbẹrun yóo ṣubú, ṣugbọn a óo gba Edomu ati Moabu lọ́wọ́ rẹ̀, ati ibi tí ó ṣe pataki jùlọ ninu ilẹ̀ àwọn ará Amoni.

42 Yóo gbógun ti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, Ijipti pàápàá kò ní lè bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

43 Yóo di aláṣẹ lórí wúrà, fadaka ati àwọn nǹkan olówó iyebíye ilẹ̀ Ijipti; àwọn ará Libia ati Etiopia yóo máa tẹ̀lé e lẹ́yìn.

44 Ṣugbọn ìròyìn kan yóo dé láti ìlà oòrùn ati àríwá tí yóo bà á lẹ́rù, yóo sì fi ibinu jáde lọ kọlu ọpọlọpọ, yóo sì pa wọ́n run.

45 Yóo kọ́ ààfin ńlá fún ara rẹ̀ ní ààrin òkun ati ní òkè mímọ́ ológo; sibẹ yóo ṣègbé, kò sì ní sí ẹni tí yóo ràn án lọ́wọ́.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12